Bo tile je pe ibo aare ati asoju
nile igbimo asofin niluu Abuja, ti waye, ti won si n mura sile fun ti gomina
lojo kesan an, osu keta, gomina tele nipinle Ogun, Oloye Olusegun Osoba ti so
pe ko si nnkan ti komisanna awon olopaa nipinle Ogun, Ahmed Illiyasu se mo
nitori o ti jawon araalu nitanmo, ti won ko si nigbekele ninu e mo.
O soro yii lakooko to n bawon
oniroyin soro niluu Abeokuta nibi to ti fee dibo lojo Satide, ose to koja yii,
o ni bi wahala ba waye nibi awon ibo naa, ki won tete mu oga olopaa naa, nitori
bo se gbabode fawon araalu nipa oro oselu.
O ni ibanuje okan lo je pe bi
komisanna naa ko se mu enikeni nibi ti won ti ju oko lu aare orileede yii,
nigba tawon yen wa se ipolongo aare niluu Abeokuta, o ni titi di akoko yii,
Iliyasu ko le so sita pe awon eeyan bayii lowo ti te nipa isele naa.
Osoba ni ti won ba le se iru nnkan
bee fun aare orileede yii, ti ko si si atejade kankan lati enu oga olopaa naa,
o ni iyen tumo si pe okunrin olopaa naa ko ye nipo lati pese abo fawon to wa
nipinle naa.
O ni aimoye awon isele lo ti waye ti
oga olopaa naa ko le sise e lati pese abo fawon araalu, pelu awon ohun ini ati
dukia won pelu.
O ni gbogbo enu loun fi so pe
Iliyasu ti kuna patapata, o si ti ta ara e danu ti ko ye ko ri be, nitori bo se
ni o n gbe seyin awon kan laise awon ise e daju.
Bee lo tun ni itiju nla lo je fun
komisanna olopaa naa nitori bi won se gbe kuro nipinle Ogun sugbon to taku pe
oun ko lo sibi ti won gbe lo naa. Bee lawon oga e ko le se nnkan le e lori, o
ni kaka ki won won gbe igbese lati mu koro tipatipa, se ni won tun se bii oba.
Ohun abuku lo pe e .
No comments:
Post a Comment