Pelu nnkan
to sele nibi ipolongo aare fegbe oselu APC to waye niluu Abeokuta, nipinle
Ogun, afaimo ki wahala maa sele ninu ibo ti yoo bere lojo Abameta, Satide, ose
yii nitori bawon toogi ti won ni Amosun ko wa se da nnkan ru ti won si ju oko
lu Aare Mohammadu Buhari.
Ipolongo
ohun to kan ipinle Ogun ni won se ni papa isere MKO, Kuto niluu Abeokuta. Lati
idaji tawon eeyan ti n de ibi ipolongo naa lawon eeyan ti mo pe ko si ki wahala
maa be sile.
Eyi to je
kayefi nibi ayeye naa ni bi Gomina Amosun se n loo, to n bo ni papa isere naa
ko to di pe eto naa bere, gbogbo iwe ipolongo Dapo Abiodun ti won gbe sinu papa
naa ni won so pe Gomina pase pe ki won gbe kuro nibe.
Iyen nikan
ko, gbogbo awon omo egbe oselu APM ni won daso egbe APC fun un, ko si to dip e ojulowo
awon omo egbe de ohun, awon toogi atawon omo eyin Amosun ti kun fon fon si papa
naa.
Iroyin tun
fi ye wa pe awon aye tawon omo eyin Dapo Abiodun tun jokoo si lawon toogi ti le
won danu, ti won sib ere si ni si fila ori won.
Bi awon
toogi Amosun se n da wahala sile ninu papa isere bee loro se ri nita gbangba,
opo awon eeyan ni won si farapa, nibi to le de Buhari ko tii de tawon mii in fi
n pada loo sile, loro ba di eni ori yo, o di ile.
Afaimo ni ko
je pe awon omo egbe APM lo po nibe, bakan ni won tun se afojudi debi pe
Abdulkabir Akinlade to je oludije gomina fegbe oselu APM naa tun wa nibe lati
je kawon omo egbe APC mo pe ko si nnkan ti won fee se.
Sugbon nigba
ti Buhari debi ipolongo naa ni wahala naa tubo po si, tawon toogi fee gba akoso
eto naa, koda Amosun gan-an fee da ara e lebi pe oun ko awon toogi wa.
Nigba ti
Buhari fee fa owo Dapo Abiodun soke gege bi oludije gomina nipinle Ogun, se
lawon omoota atawon omo eyin Amosun bere si nii ju oko lu won, se ni Amosun
gan-an sare feyin gba awon okuta.
Opo awon
alejo bii Asiwaju Bola Ahmed Tinubu, Adam Osiomohole, Gomina Kayode Fayemi. Gomina Ajumobi atawon
mii in loju gba ti fun nnkan to sele, ti won si fowo leran ti won n woo Amosun
fawon nnkan to se ati oko oro to n so si won.
No comments:
Post a Comment