Biyi Otegbeye lakooko to sabewo oselu loo ba Oba Agosasa laafin e |
Iyalenu lo je fun oba alaye Oja
tiluu Agosasa, Oba James Oyebi Elegbede nigba to sadeede ri oludije fun ipo
asoju-sofin ni ekun Yewa South,/Ipokia, Agbejoro Biyi Otegbeye laafin e.
Idi abajo ni pe latigba tawon
oloselu to maa n se ipolongo ko seyi to sabewo loo sodo oba naa ri, Otegbeye lo
si je oloselu akoko to maa se iru e, nitori e ni enu se ya oba naa, eyi to muu
fi oludije naa lokanbale pe didun ni osan yoo so fun un.
Ninu oro e, Otegbeye dupe lowo
Olorun fun idasi e Lori awon agbaagba ilu Agosasa naa pe won n wa ni alaafia,
won si tun gbe ni igbe alaafia pelu.
O loun tun dupe lowo won pe won gba
oun towo tese lati wa gba adura lenu oba alaye naa ati lati lo anfaani naa fun
ipolongo Ile si Ile toun se.
O wa mu dawon loju pe gbogbo eto to
ba to siluu nas loun yoo se toun ba fi le woke ninu ibo to n bo naa.
Opo awon Baale ati Oloye to won wa
nibe ni won dupe lowo Biyi Otegbeye fun bo se wa won wo, won wa sadura fun un
pe gbogbo ibi to ba de ni yoo ti maa ba iyi pade.
Bakan naa ni Oba Agosasa naa
sapejuwe Otegbeye gege bi ojulowo omo Yewa, nitori opo omo awon lo ti janfaani
labe e nipa awon eto idagbasoke to n se fun won.
Oba naa wa lo anfaani naa lati so
Otegbeye ninu ijoba lati ma se gbagbe awon fawon ohun imuayederun paapaa awon
ona won to ti baje atawon ohun idagbasoke mii in.
|
|||||
|
|||||
No comments:
Post a Comment