Egbe awon eleran pipa ti eka ilu
Ilaro ti fi oludije asoju-sofin labe egbe oselu APC ni ekun Yewa South/Ipokia,
Agbejoro Biyi Otegbeye lokan bale lati satileyin fun un ninu ibo to n bo pelu
idaniloju pe oun lo maa wole.
Nibi ipade egbe naa to waye lojo
Eti, Furaide ana-an nibi ti oludije naa ti loo sabewo si won ni won ti mu
idaniloju naa wa.
Ninu Alaaji Ganiyu Akinsanya to je
alaga egbe naa lo ti so pe awon ko ni ona meji ju pe kawon fi ibo won gbe Biyi
Otegbeye wole. Ati ibo Aare fun Mohammadu Buhari toun naa wa lati inu egbe
oselu APC.
Fun ipa ti Buhari naa ti ko ninu
egbe won eyi to ro awon lagbara nipase akanse ileewe awon eleran to gbogbo awon
po kaakiri orileede yii.
O sakiyesi awon ipa ti Otegbeye ti
ko lati maa fi ran awon eeyan lowo fawon olugbe Yewa lapapo.
Alaga naa tun so pe igbagbo toun ni
si Otegbeye fihan pe to ba depo naa too tubo lo anfaani yii lati fi ran awon
eeyan lowo. O wa ni awon ni nnkan meji ju pe kawon jade lati polongo fun un lo.
Nigba to n soro, Biyi Otegbeye dupe
lowo gbogbo awon eleran naa fun igbagbo ti won ni ninu oun.
O so pe oun je eda kan ti
Olorun ran lati maa mu inu awon eeyan dun. O ni oselu toun ni lati sin awon
eeyan, koun si kopa rere ninu aye won. O wa seleri pe oun too tubo maa tesiwaju
ti won ba le dibo yan oun wole.
|
No comments:
Post a Comment