| 
   | 
  
  
 
Ojo manigbagbe lojobo, Tosidee,
  ose to pari yii je niluu Abeokuta, ojo naa ni oludije gomina labe egbe oselu
  ADC, Gboyega Nasir Isiaka topo mo si GNI atawon egbe e se ipolongo ita  
gbangba. 
Ko sibi tawon omo egbe naa wa
  nipinle Ogun, koda lawon ipinle yooku lorileede yii ti won ko wa sibi ayeye
  naa pelu aso egbejoda. 
Se nibi ipago ti won lo naa kun
  fonfon, to fi je pe binu se kun lawon ita naa ko gbero fawon eeyan, ka maa
  paro tan ara wa je ko seni to gba agbegbe ilu Abeokuta koja ti ko mo pe egbe
  oselu ADC n se nnkan lojo naa. 
Pelu bawon eeyan se po to ni won
  dibo gomina won fun GNI, ko ye ki okunrin naa maa sise agbara mo, ko kan maa
  femi igbagbo gbe ni. 
Nibi ti ipolongo itagbangba naa
  fun de awon ilu  mon on ka olorin naa wa sere fun won, awon bii Saidi
  Osupa, Small London atawon olorin min in, won tun je ki ayeye naa tun
  larinrin. 
Bakan naa lawon alatileyin awon
  oludije fawon ipo to ku ninu egbe naa tun wa lati wa saponle awon eeyan won
  lojo naa. 
Bi inu GNI se dun to, ko se e fenu
  so, ninu oro e lakooko to n bawon eeyan soro, oludije gomina labe egbe oselu
  ADC so pe o da oun loju pelu ase Olorun pe egbe oselu ADC lo maa wole fawon
  gbogbo ipo ti won dije fun ninu ibo to n bo naa. 
O so pe oun gbo pe awon kan ti n
  murasile lati se magomago lakooko idibo to n bo naa sugbon oun ro iru awon to
  fee gbe igbese bee lati jawo nitori ibo to n bo yii ko nii faye iru e sile. 
O ni enikeni towo ba te yoo foju
  winna ofin ijoba. O ni erongba awon ni lati mu ipinle Ogun dagba si ati lati
  te siwaju ninu awon ise idagbasoke. 
O wa so pelu idaniloju pe oun ko
  nii doju tawon eeyan oun atawon eeyan ipinle Ogun toun ba fi le woke ninu
  egbe ibo ti yoo waye lojo keji, osu keta, odun yii. 
Lara awon to tun wa nibe lojo naa
  ni alaga apapo fegbe oselu ADC,Ralph Nwosu atawon agbaagba mii in ninu egbe
  naa. 
  | 
 

No comments:
Post a Comment