Ori ko Dapo Abiodun yo lowo awon to fee pa a l’Abeokuta -Won lo lowo awon APM ninu - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday 1 February 2019

Ori ko Dapo Abiodun yo lowo awon to fee pa a l’Abeokuta -Won lo lowo awon APM ninu

Dapo Abiodun

Se loro di bo o lo ko ya fun mi lagbegbe Ita Elega, losan ana an nigba tawon omoota oloselu ti won so pe Onarebu Mikky Kazeem to n soju Abeokuta North. Odeda ati Obafemi nile igbimo asoju-sofin niluu Abuja saaju wa doju ija ko awon omo egbe  oselu APC nibi ipolongo ti won n see niluu Abeokuta.

Gege bi atejade ti Ogbeni Tunde Oladunjoye to je akowe ipolongo fegbe oselu APC nipinle Ogun fi sita, o ni opelope awon agbofinro atawon alaabo ilu ti won ja raburabu ni ko je ki wahala naa buru koja bi won se so lo.

O salaye pe omo ile igbimo asoju-sofin yii to tun jade lati dije labe oselu APM iyen Mikky lo saaju awon eeyan naa eyi tawon mo pe Gomina Ibikunle Amosun lo ran won wa sibi isele naa ni nnkan bii aago kan koja ogun iseju losan yii.

Bee naa lo so pe orisirisii awon ohun ija oloro lawon eeyan naa mu dani lati fi se awon eeyan wa nijamba paapaa julo Omooba Dapo Abiodun to je oludije gomina ati igbakeji e, Arabinrin Noimot Oyedele ti won soro lowo lakooko naa.

O wa gboriyin fun igboya tawon omo egbe APC fun bi won se tu jade laiberu lati wa koja awon eeyan naa paapaa awon alaabo ilu.

Bakan naa lo so pe laaaro yii lawon ti koko gbo pe nitori bi Dapo Abiodun se n ri atileyin awon ati bi won se jade lakooko ipolongo e ti woodu si woodu nijoba ibile Abeokuta North, o ni won ti pinnu lati gba emi okunrin naa pelu ota ibon.

Bee lo so pe awon ti gbo tele ninu ipade ti won se pe alaga ijoba ibile meje atawon kanselo ti won wa leyin Dapo Abiodun ni won yoo le danu

Oladunjoye wa mu wa si iranti pe ni nnkan bi ose meloo kan seyin lawon ti pariwo sita pe awon kan ti gbimo po lati maa da ipolongo Dapo Abiodun ru,ti egbe awon si pe oga agba awon olopaa lati se iwadi lee lori nitori bi wahala seen waye lenu ojo meta yii, ko bojumu.

O wa mu da awon araalu loju pe ki won fokanbale ko ni sewu lakooko ipolongo won bee lo tun ni ki won ma beru. Ibo to fee waye yoo so nipa ibo ki i se nipa ota ibon

O wa ke si Aare Mohammadu Buhari lati da si nnkan to n sele ki won si towo Gomina Amosun boso.












No comments:

Post a Comment

Pages