Lati ojo Aje, Monde, ose yii ni
nnkan ko ti rogbo nijoba ibile idagbasoke Ifesowapo, ni Ogun Waterside, nipinle Ogun, nitori bi
won se lawon kanselo kan gbiyanju lati yo alaga won, Onarebu Femi Onakoya,
nitori o darapo mo oludije gomina labe egbe oselu APC iyen Omooba Dapo Abiodun.
Gege bi a se gbo, won ni nitori
okunrin alaga ijoba ibile idagbasoke maa n kopa lawon ipolongo kaunpeeni ti
Dapo Abiodun maa n se, idi niyii ti won fi lawon kanselo marun un ti won wa
labe se gbimopo lati le danu.
Won ni se lawon kanselo naa pe akowe
ile igbimo won pe ipade pajawiri nibi ti won yoo ti se ipade lati mu ipinnu won
se sugbon ti won ni akowe naa yari pe oun ko le se iru nnkan bee.
Bee la tun gbo pe nigba ti won rii
pe nnkan naa ko seese se ni won lo si Abeokuta pelu ileri pe awon yoo pe ipade
naa fun ara won. Ni bayii, Femi Onanuga ti fi aidunnu e han lori igbese tawon
kanselo e yii fee gbe gege bi eyi ti ko tona labe ofin.
Ninu atejade kan to fi sita lo ti
salaye pe lojo Aje, Monde, ojo kejidinlogbon, osu yii lawon kanselo marun un
kan gbimo po pelu awon alagbara kan niluu Abeokuta lati yo oun pelu awon meta
kan nipo nitori awon satileyin fun Dapo Abiodun gege bi oludije fun ipo gomina
labe egbe oselu APC.
Awon yooku to ni oro kan ni igbakeji
e, Alaaji Tajudeen Otuyiga, atawon kanselo meji. O ni won kuna lati gbe igbese
naa nitori ko siwe lati pakiyesi won si iyonipo, depodepo pe won yoo ni kawon
wa so tenu won.
O ni nitori awon ko tele won lo sinu
egbe oselu APM ni won se n lo agbara le
awon lori, egbe to je pe ibo to n bo le won danu, gbogbo ona lo si so pe won n
wa lati da wahala sile nipinle Ogun. O wa ro awon eeyan e lati gba alaafia laaye,
nitori gbogbo erongba won lati yo oun ko le se e se.
Bakan naa ni egbe oselu APC nipinle Ogun naa
ti so pe igbese lati yo alaga atawon eeyan e ko bofinmu.
No comments:
Post a Comment