Adari agba ipolongo fun Buhari ati
Osibajo nipinle Eko, Onarebu Moshood Adegoke Salvador ti so pe ise sese bere
lati maa polongo ibo lati ile bo sile fun oludije gomina labe egbe oselu APC,
Ogbeni Babajide Sanwo-Olu gege bi ileri toun se.
O soro yii lakooko ti won fa
moto meta, iwe ati aso kale fun oludije naa, eyi to waye nu ofiisi egbe naa to
wa ni Maryland niluu Eko.
O so pe ko si akoko kankan lati fi
sofo mo ati gege bi awon eeyan se mo oun pe toun ba seleri, oun yoo rii pe oun
muse.
Idi niyii to fi so pe ipolongo ti
bere laisi idiwo kankan o si da oun loju Sanwo-Olu to je oludije gomina labe
egbe oselu APC ni yoo woke ninu ibo ti yoo waye ninu osu keta.
Nigba to n so nipa awon ebun ti won
fa kale naa, Okunrin naa so pe awon gbe igbese naa lati fi satileyin fun
oludije naa lati le je ki ipolongo naa tubo rinle daadaa.
O wa ro awon omo egbe lati rii pe
won satileyin daadaa fun oludije won yii lati fi le jawe olubori. Pelu
idaniloju pe didun losan yoo so leyin idibo.
Bee naa lo tun gba awon niyanju lati
ri pe won gba kaadi alalope won iyen PCV, eyi ni yoo fun won loore ofe lati
dibo lojo naa.
Ninu oro Babajide Sanwo-Olu, nibi
ayeye naa, o dupe pupo lowo awon eeyan ati egbe naa fun ohun ijoju ti won
se foun.
Bee lo so pe oun ko nii je
afibisuoloore toun ba wole di gomina, o tun ranwon leti pe ki won ma se so ibo
won nu fun ti aare ti won yoo koko di, o ni Mohammadu Buhari tawon fa kale naa
ni ki won dibo fun un.
Oun naa tun ran won leti bi kaadi
idibo se see pataki to feni ti ko ba ti gba, o wa so pelu idaniloju pe oun ni
Olorun yoo lo lati wole ibo naa.
Pelu amoran pe kawon araalu ma se
faye gba gbogbo nnkan to ba le fee da wahala sile lojo ibo, nitori ibo alaafia
ni yoo je.
No comments:
Post a Comment