Remmy Hazzan |
Agbenuso fun oludije ipo gomina labe egbe oselu APC
nipinle Ogun iyen Dapo Abiodun, ni Onarebu Remmy Hazzan, eni to ti figba kan je
igbakeji olori nile igbimo asofin nipinle naa. Laipe yii lokunrin naa ba
oniroyin wa soro nipa wahala to n sele latigba yi egbe naa ti bere ipolongo,
nibi to ti fesun kan Gomina Amosun gege bi eni to n lo egbe oselu APM lati maa
da ipolongo won ru Awon nnkan to ba wa so niyii.
Ohun to da wahala sile latigba taa ti
bere ipolongo
Ohun ti mo
ri si ko ju pe eni to je gege bi gomina wa nipinle Ogun,Ibikunle Amosun ko ni
amumora, ko ni emi ifarada taa fi n wo nnkan pe ki i se gbogbo igba ni eeyan
maa n huwa ohun ti owo ni ko to, maa fi gogo faa.
Nitori eto
ti egbe se labele lati fi fa omo oye sile ko lo bi gomina se n fee, latigba naa
ni awuyewuye ede aiyede ti n sele, a si
rii pe gomina ti n fawon to n ti won leyin ni idaniloju pe awon yoo ja kinni
yen gba fun won ti ko si ri bee mo.
Gbogbo eyi
taa n ri bayii bigba ti won ba ni mi o rii gba lona ti mo le rigba, amo mo maa
fi tipa gba a tabi ki n wu iwa kaka ki eku ma je sese, maa fi sawadanu. Ohun ti
a ri si oro yii gele niyen.
Nitori
Olorun lo n fi eeyan sipo, ti Gomina baa ranti daadaa, a a ri pe bi oun gan se
dori aleefa, ki i se mi mon on se tie, bi ko se bi Olorun se fun un, ka ni bii
opolopo eeyan se n ro nigba naa laaarin Gboyega Nasir Isiaka ati Olurin, okan ninu won ni ko ba se
gomina nigba naa, amo won ni eeyan sun o gbagbe, ka fi eyi to ku sile bee.
Nipa ifokanbale araalu lori ibo to n
bo
Ajo to n
seto aabo ni awa ti ke gbajare loo ba lopo igba, ti akosile si ti wa pe a se,
tiru igbese bee si wa, a nigbagbo pe eyi to to ati eyi to ye ni won maa se, bi
a ba si rii ninu awon to wa nidi e yala awon olopaa ni o tabi ti odo awon otelemuye
to fee dabi eni pe to fee dabi eni pe o fee padi apo po mo awon ohun to n se
ijanba bayii, kawon to wa loke ba wa wo bi won yoo se gbe awon eeyan naa kuro
nipinle Ogun.
Igbagbo wa ni pe bawon to wa nidi aabo ba se nnkan to to, ko si
nnkan ti enikan le se, aabo a wa,alaafia a si joba.
Ipa tawon olopaa ti ko lori awon
wahala to ti sele
A n ri awon
igbese to jo pe won fee se, lawon ifarahan kan tabi meji to fihan pe nnkankan
fa won seyin, ohun to je ka so bee ni pe nipa ti wahala to sele niluu Abeokuta,
ti gbajare si loo sodo awon olopaa, a rii pea won ta n pe ni Federal SARS, won
yoju a tun ri awon otelemuye die naa pelu awon to n ba ipolowo wa jade
To
ba je ibi ti, gege bi a se n ro bo se ye ko ri, gbogbo ona to ye ki irinajo wa
ye ko gba lo ye ka maa ri pe igbaradi awon to seto aabo naa ko faramo bo se n
loo, sugbon a ko le so pato pe eni bayii la fee fi esun kan.
Ohun lo fa ti
oludije labe egbe APC funra e se seto lati fiwe ehonu han si oga agba patapata
fawon olopaa lorile ede yii, ki won le rii pe ohun ti agbenuso fun egbe ati
agbenuso fun oludije n so latigba taa ti n ba kinni yii bo, ki i se lasan
nitori gbogbo aworan taa fi le se eri lati fi gbe leta naa leyin.Iha ti won wa
ko si eyii yoo yato si eyii taa ti se.
Lori wahala to sele laarin APC ati
APM niluu Abeokuta.
E e ba wa
beeere lowo won pe n je won fi to awon olopaa tabi awon eleto aabo pea won fee
se ipolongo ibo lojo naa ni Abeokuta.
Nitori ki
awa to bere, nigba taa jokoo pe bawo la se fee rin, nibo la maa koko lo, ara
awon nnkan ta se ni lati kiyesi ara, ibi ti egbe mii in ba n loo,a ko gbodo loo
sibe, ko ma baa si gbon-mi- si- omi- ko-to, ara awon iwe igbekale taa mu dani
tawon APM pelu, aridaju si w ape gbogbo ojo ti won n ba lo si agbegbe kan, awa
ko ni ni nnkan se nibe.
Igba ti o ye
ka lo si Abeokuta, a rii pe o gbooro, ti Gomina si ti fenu hale fawon to n tele
won pe a ko le se ipolongo ibo wa ni Abeokuta, ko si nnkan ti APC le fi wa iru
sowo, sugbon awa wo bee, amo bawon eeyan se yo mo wa, a roo pe o se Gomina
atawon eeyan e ni kayefi, pe awon ko mo pe bayii lo se ri.
Iyen sele
nigba ta koko se ipolongo, ni Mikky Kazeem, eni to n dije fun ipo asoju- sofin
labe egbe oselu APM fun ekun Abeokuta North, Odeda ati Obafemi Owode ba so pe
oun naa fee se ipolongo ibo ni Abeokuta North ni ojo kan naa taa n se tiwa.
Ohun to tumo
si ni pe ki i se ipolongo ibo ni won fee se, bi ko se forifori lati da nnkan
ru.Funra Dapo Abiodun lo pe komisanna awon olopaa nipinle Ogun, to si so fun
un.
Komisanna
loun maa so fun un pe ko le se iru e, nitori pe awa ti so fun oun pe a fee se
ipolongo ibo, oun si ni akosile e lowo, bawo wa ni komisanna se rin in ti Mikky
si tun wa nita to loun polongo ibo, ki awon eeyan ba wa fi oye gbe. Aje ke lana
an, omo ku loni in, mi o ni so ju bee lo.
Gbogbo wahala yen ko di ipolongo wa
lowo
Iyen lo faa
ta fi n je ki gbogbo awon eeyan mo pe ki lohun to n be nigbo, to n dun mahuru mahuru, yoo kan maa dun ni, nitori
nnkan ti yoo sele yoo sele.
Nitori leyin
gbogbo wahala Abeokuta yen ipolongo ibo si waye, ka ni bi won se da nnkan ru,
la sa lo ni yoo soro lati pada sugbon a ti je kawon eeyan wa mo pe ko si nnkan
teeyan kan yoo feeyan kan se.
Won ki i pe eeyan lomo ale nile baba e, ayafi
tonitihun ba fowo osi juwe ile,ki awon eeyan wa ki ara won laya, ipolongo si n
tesiwaju.Ko si nnkan to da wa duro, eni to ba tapa sofin, lofin maa mu.
No comments:
Post a Comment