Apostle Biodun Sanyaolu |
Laipe yii ni okunrin
naa ba oniroyin wa soro lori nnkan to ni lokan, bi o ba wole gege bi Seneto
ninu ibo to n bo lojo kerindinlogun, osu keji. Ohun to ba wa so niyii.
Oruko mi ni
Apostle Biodun Sanyaolu, ti mo je oludije fun asofin agba nile igbimo asofin
niluu Abuja fun ekun Ogun Central labe egbe oselu PDP.
Ohun ti mo ni fawon eeyan mi ni Ogun
Central
Ni akoko, a
ni lati mo pe opolopo awon oloselu ni won ti seleri fawon eeyan sugbon ti won
ti da won nipase aimu ileri won se. Fun idi eyi ohun ti mo koko ni ti mo fi se
atona ise iranse mi lati lo se ni Abuja ni okan lati loo soju fawon eeyan mi
pelu iberu Olorun. Eni to maa to, gbodo ni Iberu Olorun.
Awon ohun ti
Olorun ti lo wa fun leyin paapaa nigba taa n se alamojuto ileese idagbasoke ati
alajeseku nipinle Ogun.Opolopo lawon nnkan ti Olorun ti lo wa fun nigba
yen o lo mu mi gbaradi fawon ise ti a
fee loo se ti a ba de Abuja
Ise ile
igbimo asofin ni lati loo je asoju, ati oluso fawon eeyan ti wa, ti a ba si wo
awon oloyinbo so itumo demokiresi gege bi ijoba awon eeyan, latodo awon eeyan
ati fawon eeyan.
A o rii pe
nnkan to se koko ninu oro naa ni awon eeyan, a maa fi itura awon eeyan se gbogi
ninu ise taa fee lo se. Ona ti a fee gba se, akoko ni taa ba wo awon to ti se
seneto siwaju, ko tii si awon to fara ro wa bi odun mejo si mewaa seyin ni
agbegbe ibi ti won ti dibo. Ogun Central yii to ye ki won maa ri won wo lati mo
awon nnkan to je isoro wa, ti won ti ba pade, lopolopo igba.
Igba ti won
de be, won ko fi anfaani sile lati maa yoju sawon eeyan to dibo fun won
loorekoore. Eto temi wa fee se ni pe akoko yoo maa wa fun ikansini laarin emi
ati won. O kere ju eemeta laarin odun kan.
Ohun ni yoo
maa je ki n so fun bile igbimo asofin se ri, awon nnkan bayibayi la n se o,
lati mo ero won, nitori e ma gbagbe wi pe awon ni mo fee loo soju fun.
Won gbodo mo
kin ni a n se lohun,emi naa si gbodo mo kin ni ero won lori nnkan taa n se lohun.
Awon eeyan mi gbodo rii pe ohun tawon n
fee ni mo n so nibe. Nitori agbenuso won ni mo je, gbogbo won ko si lanfaani
lati wa nibe, ni won se ni ki n loo ma soju won nibe. Ohun ti won ba si n fee
ni mo ni lati loo soju won nibe.
Yato si eyi
kin ni kan wa ti a n pe akanse ise agbegbe, latigba ti mo ti denu oselu, mo si
ti pe die naa, gbogbo awon ti won ti je seneto ni Ogun Central yii, inu oselu
ni won ba mi.
Ko ti si omo
ile igbimo asofin agba kan to pada wale to wa beeere lowo wa pe ise akanse
tawon fee se o, ki la n fee, bi a ba si beeere lowo awon eeyan, o se e se ko je
pe nnkan tawa n fee lati se ko ma je nnkan ti won n fee. Lati jo soro papo ise
ti won n fee nijoba ibile won, ise ti won ba so pe won n fee, ohun la maa fi
sinu eto isuna akanse ise agbegbe wa.
Gege bi oye
ti mo ni nigba ti mo n se alabojuto ileese idagbasoke agbegbe ati alajeseku ni
pe ijoba meta ni won fowo si ni Naijiria, ijoba apapo, tipinle ati ijoba ibile.
Mo se akiyesi pe okan naa naa wa ti won n pe ni eyi ti won ko ka kun iyen ni
awon eeyan.
Bi e ba wo
daadaa ni agbegbe yin ti e ba ni egbe idagbasoke nibe, awon ni won mo nnkan to
n dun won ni agbegbe yin,opolopo won osise feyinti lo kun inu won, ti won ki i
se awon to n wa owo ijoba, won a wa maa dawo lati se nnkan to ye kijoba se fun
won. Emi roo pe ofin taa n lo, o gbodo ka awon eeyan naa kun. A ni lati fi
nnkan sawon ofin naa, kin ni nnkan ti mo lero lati fi si, akoko, gbogbo ijoba
bii apapo, ipinle ati ibile, ki won maa gba erongba okan awon eeyan naa si ohun
ti won maa fi si eto isuna won gege bi awon eeyan to mo ofin.
Eleekeji,
ipago awon oba, se e mo pe nini alokesan, o ni nnkan ti won yoo sile fawon oba,
bakan naa ida kan wa nibe to wa fun ise akanse agbegbe, awon alaga yen ko rii
gba, awon to si ri gba, won ko kowo naa si ise agbegbe , awon nnkan yen naa wa
ti a maa fi sinu abadofin ti a ba de ohun.
Lara awon
nnkan ti mo tun fee loo se, egbe alajeseku, bi a ba woo, paapaa laarin awon
osise ijoba, bi a ba ri eyi to kole ra moto yato sawon to ri owo ji o, mejo si
mesan an, egbe alajeseku lo gbe won.
Oun naa lo n
gbe awon oloja, koda awa ti a je agbe paapaa, afaramo egbe alajeseku kan si
omii in. lati yawo ninu egbe alajeseku anfaani to wa ninu e po, lakoko, o rorun
lati ya. Bi o ba fee yawo ni banki, won a ni ko loo mu iwe ile e wa, tabi ko lo
mu omo e ti won ko ti jabale e wa. Gbogbo nnkan ti won ba beeere o le maa ri
laaarin odun kan si meji.
Sugbon egbe
alajeseku laaarin ojo perete, wa a gba owo naa, to ba si tun se daadaa, won tun
le ya e lowo. Ele owo to wa nibe dara ju ti banki lo. Anfaani mii in paapaa awon osise ijoba, o rorun lati gba owo
won pada, ki I se bi ti ipinle Ogun tijoba yo owo won ti ko da pada fun won. To
si n paro pe oun ko je osise ijoba lowo.
Ki lo de
tijoba apapo, ti a ko le gbofin kale pe owo ti a ba pa o, bo ti wu ko kere to,
ki Central Bank ko maa fawon egbe
alajeseku, won yoo si maa da pada ni owo ti ko ni ni won lara nitori pe yoo le
mu ise ati osi kuro laaarin awon eeyan nilu wa. E woo, nnkan taa fee se, o po
gan-an ni.
Ko si iberu fun mi ninu awon taa jo n
dupo seneto
Ko si enikan
to je iberu fun mi ninu gbogbo awon to jade lati dupo seneto ni Ogun Central,,
bi a ba woo ni otito ati bo se ye, bi onikaluku se je ni Egba, se laa jinna si
ara wa, nitori pe ibi onikaluku oto ni, bi won ba n so nipa iwe itan Egba, ni
se ni won maa so nipa itan baba to bi awon babanla temi.
Fun apeere,
adajo akoko ni kootu ibile ,kositomari
ni Egba yii, Baba to bi baba baba mi ni. E n gbo nigba kan ti won n so ijoba Egba
United, baba to bi baba mi yii, okan ninu awon agbaagba.
Ibi si maa n
ran eeyan pupo yato siyen ko seyi to kawe ju mi lo ninu gbogbo awon to fee se
Seneto yii, Bee ni mo tun je oga gbogbo won, ati Amosun, Titi Oseni, oga won ni
mo je ninu oselu. Owo mi yii ni won de si, awa ni Olorun si lo lati so won da
nnkan ti won da loni in ninu oselu.
Titi Oseni
ti se ri, Amosun naa ti se seneto ri, ko to wa se gomina, ha haa se ile ti won
nikan ni,won maa n korin nigba kan nile Egba, won a si gongo so nile Amodemaja
sugbon won ti yii pad ape ki gongo so nile elomii in, ko ma je ile Amodemaja
mo, se Amosun nikan lo wa nibe, nigba to se gomina ki lo mu wa fun wa.
A bi ki
lo gbagbe sohun, to fee lo mu, se ni mo we, ti mo yan kainkain. Mo fee ki e loo
se iwadi mi lodo awon egbe idagbasoke pe eni to je komisanna akoko fun ileese,
ki lo se fun yin, awon ohun taa se nigba naa ni won si n se di akoko yii, awon
nnkan ti a le raye se, lawon naa n se bayi.ohun to wa lode bayii ni ta ni e, ki
lo ti se ri? Emi lawon itan ti mo fi le so pe mo ti se bayii.
Nitori idi
eyi, ko si iberu fun mi yato siyen, bi e ba wo, awon wo ni egbe won fidi mule,
Amosun o fee dibo ninu egbe APC, o gbese kan sinu egbe APC, o gbe kan si APM,
se eeyan gidi se iru e.
E je ki n so
kin ni kan fun yin pe lagbara Olorun emi ni mo maa wole, Amosun le ni owo o,
nitori owo wa lowo e, sugbon e ma gbagbe itan Dafidi ati Goliat ni oro to wa nile bayii.
Igbagbo ninu ajo INEC
Ohun ti ajo
naa n se niluu Abuja, ko fi okan wa bale, nitori bi awa se se nigba aye
Jonathan ko dabi eni pea won Buhari fee se be. Fun apeeere Arabinrin ti won n
fa oro e lowo, eeyan Buhari ni, eeyan e ko, pe oun ni ko jokoo, ko sajopo esi
ibo, to ba tie soooto, sawon eeyan maa gbagbo.
Bi won ba n
fee alaafia, ki lo de ti won ko so pe oro yii ko fee obinrin, e je ka fi elomii
in sile, nitori idi eyi igbagbo taa ni ninu won ko po. Sugbon a ni gbagbo ninu
awon eeyan ti won sise ni INEC.
Awon naa a ri I wi pe inira to wa lode yii po,
won ko si ni fee gbabode pe ki won wole.
Amoran
Mo fee ro
gbogbo awon olugbe aarin gungun Egba, ti won wa nijoba ibile mefa Abeokuta
South, Abeokuta North, Ewekoro, Ifo, Odeda ati Obafemi Owode pe ibo to n bo
lookan yii, ki won ro daadaa, egbe PDP ti se ri, amo biluu se ri, APC naa ti
se, won ni bi obinrin ko ba dan ile oko meji wo, awon naa yoo ti ri bi inira se
laarin igboro, mo be won ki won dibo fun PDP, egbe ti won ti mo tete to se
daadaa.
Enikeni ti ko ba ni iberu Olorun, ki won ma dibo fun un, ati pe owo ko
ni oro ibo yii o, ki won ma ta ibo won,
sugbon ki won wo bi onikaluku ba se ri.
No comments:
Post a Comment