Gomina Ambode |
Bo tile je
pe oni ko ni awuyewuye pe awon omo ile igbimo asofin naa n wona lati yo gomina
ohun, sugbon ti won ni ko si nnkan to jo o, laimo pe panpe ti won yoo fi mu
lese ni won n wa. Ni bayii, won ti ri
panpe naa, ona lati yo lo ku fun un.
Ohun taa gbo
ni pe lakooko to ye ki Ambode wa ka eto isuna seti awon omo ile igbimo asofin
e, se lo ko ti ko yoju,leta lo fi ranse sawon eeyan naa, ti won lo lodi si bi
won se n se tele. Arifin ati egbin nla ni won ni gomina naa fi kan won, tawon
naa si n wo o niran.
Eyi ni won
so pe o faa, ti olori ile igbimo asofin, Onarebu Mudasiru Obasa fi so fawon
yooku e pe ki won maa ti je kawon gbe igbese kankan, ki won je kawon fun un
laaye lati wa so tenu e lori eto isuna odun yii, ti won lo ti n na laigba ase.
Olori ile
igbimo asofin naa so pe o ye ki awon bii adajo agba komisanna feto isuna ati
komisanna to n ri si bojeti ati oro aje gba gomina lamoran lati ma se gbe
igbese to gbe ohun.
O ni nnkan
tawon fee ki awon araalu mo ni pe eto isuna iyen bojeti tawon ko tii fowo si ni
gomina ti kowo bo, idi niyii tawon ko fi da Ambode lohun lojo kokanlelogun, osu
yii, nigba to ranse pe awon lori e.
O ni idi
niyii tawon fi ranse pe lati wa so nnkan to ri lobe, to fi wa iru sowo, lori
oro agbekale eto isuna ti ko yoju naa.O ni nnkan tawon mo ni pe ko to di pe won
bere si nii nawo ijoba, ohun to ye ni lati koko gbe wa si iwaju ile igbimo
asofin lati gbe yewo. O ni awon le bere igbese lati yo o nipo nipa kiko bowe
sugbon awon fee se suuru lati fun un ni akoko mii in.
No comments:
Post a Comment