![]() |
Seneto Iyabo Anisulowo |
Agba oloselu obinrin nni, Seneto Iyabo Anisulowo ti so pe titi di akoko yii egbe oselu APC loun wa sugbon nnkan to se pataki to je oun logun ni bi Yewa yoo se di gomina nipinle Ogun, ninu ibo to n bo ninu osu keta odun yii.
O soro yii
nigba to n ba oniroyin wa soro, o so pe ki i se idunnu awon omo won to kuro
ninu egbe oselu APC bo sinu APM bi ko se ireje ni won ko, ti won si sa fun un.
O so pe lati
bi odun meloo kan seyin ni Gomina Ibikunle Amosun ti seleri pe boun ba ti kuro
nipo Yewa loun yoo fa ipo naa le lowo, to si mura lati mu ileri e se.
O ni iyalenu
lo je fawon bawon kan se fowo ola gba awon loju to je pe oludije tawon dibo yan
an lakooko pamari iyen Abdul Kabir Akinlade gege bi oludije gomina fegbe oselu
APC nipinle Ogun, ti won daanu, ti won si mu elomii in, o ni nnkan to buru jai
ni.
Iyabo
Anisulowo tun salaye pe bi won ba ni ka woo, lati nnkan bii ogoji odun le die
seyin, tipinle Ogun ti wa ko ti si enikankan ti won fun ni oore- ofe lati di
gomina, idi niyii tawon omoleyin won fi yari pe bi egbe oselu APC ko ba fun won
ni tikeeti, won yoo gba egbe mii in lo, ti won si ko ara won lo si APM.
Obinrin naa
pelu ireje ti won n se naa, awon si wa ninu egbe APC nitori awon ko le sise, ki
elomii in wa je, awon ko le kole kenikan wa le awon jade.
O ni iyalenu
lo je pe ko sibi tawon omo naa de, ti won ko tewogba won fun ipolongo, koda to
fi mo oganjo oru lo ni awon eeyan fi maa n duro de won, nitori gbogbo araalu mo
pe ireje nla ni. O ni loooto oun ko tele won lo si iponlpngo o, sugbon iroyin
tawon gbo ni pe awon araalu ko foro won sere.
Iyabo
Anisulowo tun so pe awon lawon so fun Gomina Amosun pe enikeni to ba fee mu
lati odo won, gbodo je eni ti yoo gboro sii lenu, ti yoo tesiwaju ise nibi ti
gomina ba de, oun lawon fee, o ni nigba ti won si sayewo gbogbo awon to fee
dije, ti won sir ii pe Akinlade koju osuwon, lawon naa se fowo sii.
O ni erongba
awon ni Ogun West ni ki gomina wa si odo won lakooko yii, nitori awon eya yooku
naa ti se, awon nikan lo ku. Lati pe GNI ati Akinlade ti won jo n dije jokoo
papo, lati bawon soro, obinrin naa ni kin ni naa soro lakooko tawon wa yii.
O ni GNI naa
ti wa sodo oun, toun si fun un nimoran, o ni eni ti nnkan n wu, yoo kan gba
imoran naa ni. O ni oun ni omo Yewa akoko to gba tikeeti lati dije fun ipo
gomina ninu egbe oselu APP, latigba naa lo ni awon omo won ti n tiraka lati
depo naa, amo tawon arenije ko je.
Gege bo se wi, titi di odun 1991,bi
Yewa se fe to, meji ni won pin ijoba ibile won si iyen Egbado South ati Yewa
North. Gbogbo so igba naa si ree, oun ni akowe nijoba ibile Egbado South.
O ni nigba ti ijoba apapo da awon
ijoba ibile si sile leemeji, won ko fawon rara sugbon lodun 1996 ni Olorun lo
oun atawon kan lati da ijoba ibile meji mii in sile iyen Ipokia ati Imeko Afon.
O ni pelu bi Ado-Odo-Ota naa se wo o,
lo je ko je ijoba ibile marun un, eyi to si fawon lore ofe nipa ibo didi ati ni
asoju.
Bakan naa lo tun so pe oun ni omo
Yewa akoko to koko gba tikeeti lati dije fun ipo gomina lodun 1999 labe egbe
oselu APP, eyi ti won jo wa parapo di AD/APP to fi fun Oloye Segun Osoba laye
lati di gomina leekeji.
Obinrin naa
wa gba gbogbo awon omo Yewa nimoran lati fimo sokan fun ibo to n wa lona naa,
ki won si je ki eto won ti won ti n ja fun lati bi odun mejilelogoji le te won
lowo.
No comments:
Post a Comment