Ojogbon Abdul Ganiyu Olayinka Raji, to je alabojuto fajo INEC ti won sese gbe wa sipinle Ogun ti seleri pe ko ni si magomago tabi ojusaju ninu ibo to n bo nipinle naa.
O soro yii
lakooko to n ba awon oniroyin soro ni ofiisi e, nigba to fee bere ise nipinle
naa. Okunrin naa so pe oun fee kawon araalu nigbagbo ninu ajo naa fun ibo to n
bo ohun nitori pe gbogbo agbara lawon yoo sa lati rii pe ibo naa loo ni
iloworose.
Ojogbon naa
tun salaye pe koun to de ipinle Ogun lawon osise abe oun ti bere ise fun
igbaradi ibo naa ati pe ibi ti won ba de loun naa yoo ti te siwaju.
O ni lakooko
perete to ku yii, oun yoo sa agbara oun lati ba awon otokulu ilu se ipade po
lati rii pe ifowosopo yoo wa laarin won paapaa awon oloselu.
Bee lo tun
so pe awon yoo tun sise po pelu awon alaabo ilu lati ri pe awon ibo naa kese
jari. O wa lo anfaani naa lati bawon araalu soro nipa kaadi idibo won pe eni ti
ko ba tii gba ko ya tete lo gba bayii lawon ibudo ti won ti la sile fun won pe
ki won ti waa gba.
No comments:
Post a Comment