Seneto Iyabo Anisulowo, to je agba
oselu nipinle Ogun, to tun figba kan je omo ile igbimo asofin niluu Abuja, ti
so pe oro egan ko, Agbejoro Biyi Otegbeye, to n dije fun ipo asoju-sofin fun
ekun Yewa South/Ipokia labe egbe oselu APC koju osuwon lati depo naa.
Obinrin naa soro yii lakooko to n ba
oniroyin wa soro niluu Abeokuta. O so pe oludije naa je eeyan daadaa, to ko ara
e nijanu, to si tun laanu loju, nitori opo awon lo ti soore fun un, ti won si
tun jeri sii pelu.
O so pe o tipe toun ti mon on, ati
pe ileese e loun lo fun adojutofo, latigba tawon si ti n jo sise po, oun ko
figba kankan kabamo rara.
Gege bo se wi, titi di odun 1991,bi
Yewa se fee to meji ni won pin ijoba ibile won si iyen Egbado South ati Yewa
North. Gbogbo igba naa si ree, oun ni akowe nijoba ibile Egbado South.
O ni nigba ti ijoba apapo da awon
ijoba ibile si sile leemeji, won ko fawon rara sugbon lodun 1996 ni Olorun lo
oun atawon kan lati da ijoba ibile meji mii in sile iyen Ipokia ati Imeko Afon.
O ni pelu bi ti AdoOdo Ota naa se we
lo je ko je ijoba ibile marun un,eyi to si fawon lore ofe nipa ibo didi ati ni
asoju. Bakan naa lo tun so pe oun ni omo Yewa akoko to koko gba tikeeti lati
dije fun ipo gomina lodun 1999 labe egbe oselu APP, eyi ti won jo wa parapo di
AD/APP to fi fun Oloye Segun Osoba laye lati di gomina leekeji.
O ni ibi ti Akinlade to lo odun
mejila gege bi asoju-sofin ti wa naa ni KLM naa ti jade nigba ti ki i sawon
nikan lo wa nibe, nitori idi eyi, oun fi
yooku le awon oludibo lowo, nitori o ni bawon se maa n se.
Bee lo sapejuwe Otegbeye gege bi eni
to gbonran to si le se nnkan tawon eeyan e n fe, to ba depo naa.
|
|||||
|
|||||
No comments:
Post a Comment