Ko seni ti mo maa lo paati ninu eyin alatileyin mi- Biyi Otegbeye - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday 25 January 2019

Ko seni ti mo maa lo paati ninu eyin alatileyin mi- Biyi Otegbeye


                   
 Oludije asoju- sofin nile igbimo asofin niluu Abuja fun ekun Yewa South/Ipokia  labe egbe oselu APC, Agbejoro Biyi Otegbeye ti mu u da awon alatileyin loju pe ko si nnkan to n je alopati bi won ti dibo yan oun wole.

O soro yii lakooko to n bawon alatileyin e yii soro ni Ifekowajo nijoba ibile Yewa South nibi ti won ti n sagbekale awon ololufe e ti won fee sise fun un, eyi to waye ni gbongan Bimtu Amope, ni Owode Yewa, nipinle Ogun. Eyi to waye lojo ketalelogbon, osu you.


Ninu oro Oloye Ajibabi Taofeek, to je okan lara awon agba egbe naa, o so pe pataki ipade ojo naa ni lati sagbekale awon to sese darapo mo won lati gba won towo tese.

Ninu oro Biyi Otegbeye topo mo si BOT lojo naa, o koko bawon kedun awon ti won seku pa lakooko ti wahala sele lagbegbe naa pelu adura pe ki Olorun forunke won.

Bakan naa lo tun fi idunnu e han bawon se po repete nibi ipade naa, eyi to n fi lokanbale pe didun losan yoo so fegbe oselu APC ninu oro bi to n bo naa.

Otegbeye tun salaye pe ise pataki to wa niwaju awon eeyan naa ni lati tan imole egbe oselu APC kaakiri ileto, ki won si sise naa tokantokan.

O wa ki awon ti won yan naa ku oriire fun bi won se yan won, o ni bo tile je pe opo la pe sugbon die laayan, o wa gbadura pe won yoo saseyori nidi e.

Nibe naa ni Arabinrin Felicia Oni ti so pe oun setan lati sise po pelu oludije asoju- sofin won yii, o ni koda laifi oju ri oun janfaani awon nnkan to ti se fun idagbasoke.


Bee naa ni Oloye Ajibabi ti so ni tie pe iru awon eeyan bi BOT lawon fee lagbo oselu, nitori bo se n ran awon eeyan lowo, to si fee ki osi ati iponju dopin ninu aye awon eeyan.


No comments:

Post a Comment

Pages