Tunde Oladunjoye, akowe fidie
olupolongo fegbe oselu APC nipinle Ogun ti ke gbajare sita ti nnkan laburu ba
fi le sele soun, kawon eeyan ma ro loo sibomii in ju odo Gomina Ibikunle Amosun
lo nitori oun gbo pe o ti ko awon eru iku sita lati gba emi oun.
Ninu atejade ti okunrin naa fi sita
nirole yii lo ti so pe asiri bi won se ni Amosun da awon kan sita lati maa so
awon olori egbe APC paapaa julo oun, lati see won nijanba lo ti tu sawon lowo,
idi niyii tawon fi tete pariwo sita.
Oladunjoye fidi oro e mule pe enikan
lo fi nomba pe oun lori foonu to tu asiri naa, o ni bo tile je pe ki i se igba
akoko ree tawon ti n gba iru ipe bee.
O ni eyi to je pambabari e ni pe won
lawon kan to n gbimo po lati gba emi oun lati oni lo si Sannde ti won fee lo
lati gba emi oun yii. O ni nitori e loun ko se foro naa bo toun fi pariwo sita.
O tun so pe latile oun gege bii
ajafetoo nileewe titi toun fi di oloselu, oun ko bawon fa ijangbon tabi da
wahala sile ri
Bee loun yoo tesiwaju lati maa ja
fetoo awon eeyan awujo laiberu ati sojo rara
O wa pari oro e pe fun gbogbo awon
ti won gbinyanju lati se won nijanba tabi gbemi won pe emi awon ti koja bi won
roo o
O ni ki gbogbo agbaye mo pe bi nnkan
tabu ijanba ba fi le sele si awon agba egbe APC, Amosun ni ki won beeere lowo
e.
No comments:
Post a Comment