Awon agba bo won ni boju ba n se
ipin, a maa n fi han ni egbe oselu APC tipinle Ogun ti kilo fun oludije gomina
labe egbe oselu APM, Abdulkabir Akinlade lati kowo omo e boso, nipa si soro
buruku si Oloye Olusegun Osoba, nitori enu e ko gba gbogbo isokuso to n so
kaakiri.
Ninu atejade ti akowe fidihe
olupolongo fegbe naa, Tunde Oladunjoye fi sita ni won ti so pe gbogbo oro ti
oludije naa fi ranse si agba oselu naa, ko fihan bii pe oun gan-an tile gidi
jade.
Won ni pelu nnkan ti okunrin naa n
se o fihan pe iru eeyan ti oga e je loun naa, to si n tele ilana e pelu.
Nitori bi ko ba mo won ni Baba Osoba to fee maa fi ta yin yii lo so oga e di
gomina, bo tile je pee fi ibi su baba naa ni.
O ni ko ye ki Akinlade maa tori
oselu foko oro ranse si Baba agbalagba eni ogorin odun to je pe nigba to fi wa
ni gomina ipinle Ogun, boya ni o ti le jade ileewe girama.
Oladunjoye tun salaye pe awon tun fi
akoko yii so fun pe ko dake lori pe iya legbe naa fi je oun ninu ibo pamari to
waye ninu osu kewaa odun to koja, won ni iro to jinna sooto ni, nitori bawo
leeyan se le so pe oun koju osuwon fun egbe agbaboolu, sugbon ti won ko ni rii
ninu idije agbaye.
Egbe APC ni ki Akinlade bo sita
gbangba ko was fihan bo se kopa ninu idije pamari gomina to waye ninu osu kewaa
naa faraye.
Bee ni won ni ki si ooto lori nnkan
to so pe egbe oselu APC to gbaradi lati sojooro ninu ibo gomina to n bo, won
oro e ko mu ogbon wa, eru bi Dapo Abiodun to je oludije gomina APC see foojumo
gbale gege bi omoluabi lo n ba a.
Won ni amoran tawon gba oun
ati oga e, ki won maa mura sile lati se akosile bi won se nawo inakuna lori
egbe ti ko fesemule, eyi to tako ofin.
|
No comments:
Post a Comment