Olu-Itori ni Dapo Abiodun ni ki won dibo gomina ipinle Ogun fun. - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Tuesday 22 January 2019

Olu-Itori ni Dapo Abiodun ni ki won dibo gomina ipinle Ogun fun.


  Olu Itori tiluu Itori, Oba Abdul Fatai Akorede Akamo ti gba awon oba alaye to wa nijoba ibile Ewekoro atawon to n gbe lagbegbe naa nimoran lati ma se fibo gomina ti won fee di ninu osu keta sofo, ki won dibo won fun Dapo Abiodun to je oludije labe egbe oselu APC.

O soro yii lakooko ti oludije gomina naa atawon eeyan e loo sabewo sodo oba alaye naa ni aafin e ni Itori.

Oba naa so pe awon ko tii gbo nnkan gidi ri nipinle naa a figba ti egbe oselu APC gbakoso. O ni egbe yii nikan lo mu igbe aye rorun fawon eeyan ti won si tun mu idagbasoke bawon, to si derin pa awon to ku die kaato fun.

 O ni Gomina Ibikunle Amosun to sa ipa e nipa si so ipinle di otun, O ni ipinle Ogun si wa eni to tun le se ju tie lo.

O wa gboriyin fun Aare Mohammadu Buhari fawon nnkan tijoba e ti se si ijoba ibile Ewekoro. Oba Akamo tun salaye pe o se ni laaanu pe awon alaimokan n pe ni Baba go silo, o si fun won ni reluwe ati oju oko ofurufu nijoba Ewekoro, o ni bi won see pe yen ni ki won maa pe e ko si maa se nnkan rere fawon.



Ninu oro Dapo Abiodun, oludije gomina ohun, o mu da awon eeyan Itori, Oluke Orile nijoba ibile pe ileese Dangote to n se simenti yoo tun pada si agbegbe naa.

O salaye pe pelu awon iriri toun ti nipa okoowo yoo foun laye lati bawon soro, ti won ba fee pada sipinle naa.

Bakan naa lo ni ijoba oun yoo mu igbe aye rorun fawon olugbe kawon naa le janfaani ijoba awarawa kaakiri ipinle naa.



1 comment:

Pages