Aare Mohammadu Buhari |
Egbe oselu APC ipinle Ogun ti
sagbekale igbimo ti yoo gbalejo ipolongo ibo aare Mohammadu Buhari, eyi ti yoo
waye lojo kokanlelogbon, osu kin in ni, odun yii niluu Abeokuta.
Gege bi atejade ti Ogbeni Tunde
Oladunjoye, to je akowe ipolongo kiatika fegbe oselu naa nipinle Ogun fi sita
lo ti so pe onisowo nla nni, to tun je agba oselu, Owodunni Opayemi ni yoo je
alaga igbimo igbalejo naa, nibi ti won yoo tun ti gbe asia oludije fun Omooba
Dapo Abiodun, gege bi oludije gomina.
Igbese ti won gbe yii waye lori abo
ipade kan ti won se lojo Aiku, Sannde, niluu Abeokuta nibi ti Oloye Olusegun
Osoba ti dari e
Awon omo Igbimo yooku ni Senato
Gbenga Obadara, Tunji Akinosi, Dokita Yomi Majekodunmi, Agbejoro Olubukola
Onabanjo, Arabinrin Funmi Afuwape,. Semako Huyen, ati igbakeji gomina nipinle
Ogun meji tele Senato Sefiu Adegbenga Kaka, ati Oloye Segun Adesegun, to
tun je alakoso agba fun ipolongo Dapo Abiodun iyen (DACO).
Awon igbimo yii la gbo pe won yoo
sise po awon oloye afunniso fegbe oselu naa eyi ti Oloye Femi Sanusi, je
alaga won bee ni won yoo tun sise po pelu igbimo apapo egbe lati le je ki eto
naa larinrin.
A o ranti pe lose to koja lawon kan
ninu egbe naa fehonu won han lori bi won se ni ki Gomina Ibikunle Amosun je
alaga igbimo igbalejo naa gege bi ipo e ninu egbe naa nipinle Ogun.
Won se ni okunrin naa huwa to Lodi
sofin egbe nipa bo se n se ese kanle ese kan ita, ti ko sise po pelu awon
oludije tegbe fa kale, won ni ko le se alaga igbimo igbalejo naa.
Idi niyii tawon omo egbe naa se gbe
igbimo tuntun kale ti won si ti bere ise won.
|
|||||
|
|||||
No comments:
Post a Comment