Won yoo sadura ojo mejo oku Mama Doyin Aggrey onitiata - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday 18 January 2019

Won yoo sadura ojo mejo oku Mama Doyin Aggrey onitiata


 
Ojo Aiku, Sannde, ogunjo osu yii, ni won yoo sadura ojo meta oku  Iyaafin Titilayo Qudirat Aggrey to je mama okan lara gbajumo osere fiimu Yoruba nni, Doyin Aggrey.

Gege bi omo mama naa, Doyin se so sita, ilu Ikorodu ni ayeye adura ojo mejo naa yoo waye, eyi ti yoo bere ni dede aago mewaa aaro. Ladugbo Rotimi Odusanya, legbe ooteli Alomar,bositoopu Haruna, Ikorodu nipinle Eko.

Lojo Aiku, Sannde, ose to koja ni Mama naa jade laye leyin to ti lo odun marundinlaadorin laye. Ninu oro to ba wa so nipa mama naa, Doyin so pe iku naa ba oun lokanje nitori ko seni to mo pe iya naa tete le fawon sile lo bayii.

O salaye pe eni toun ko le gbagbe laelae ni, nitori ipa ribiribi to ti ko ninu aye awon omo e, Abiyamo gidi lo pe e, to si ni igboya gidi ninu Olorun.

O ni pelu bi Mama oun se padannu oko e ati meji ninu awon omo e lojo kan soso, se lokan e se giri, to si duro ti opo Olorun titi ti elemi fi gba, bee ni ko siyemeji.

O wa pari oro e pe oun ko le tun ri eni to tun le se bi iya oun, adura oun si ni pe ki Olorun forunke. Omo, ati omo omo niya naa fi saye lo. Ki Olorun foriji won.

No comments:

Post a Comment

Pages