Igbakeji oludije gomina, Oludije gomina, Dapo Abiodun ati Akimu Ambali, alaga awon osise |
Okunrin naa
soro yii, lakooko to sabewo sodo awon omo egbe naa ni ofiisi won to wa ni
Lemme, niluu Abeokuta, lojo Eti, Furaide. O so pe pelu bi ogo ti n je ti
Olorun, iderun yoo de ba awon osise lakooko toun ati pe gbogbo to ba je eto won
ni yoo maa te won lowo laifi fale rara.
Nibi abewo
to se, eyi ti Gomina tele nipinle Ogun, Oloye Olusegun Osoba ti saaju awon omo
egbe oselu APC loo pade awon osise naa lo ti so pe gbogbo agbara oun loun yoo
lati ri I pe ajosepo to danmoran wa lati odo awon osisr ati ijoba, bee ni ko ni
maa se gbonmi si omi ko to.
Dapo Abiodun
so pe tinu tijoba ba gun rege , ise awon osise ijoba ni to ba ri ni idakeji
awon naa ni, nitori ipa ti won n ko kere, idi niyii tijoba e ko fi ni fowo rowo
seyin, ti won le satileyin fun un lati di gomina nipinle naa.
Bee lo so pe
awon yoo satunse lori wahala to n sele lori awon olori osise, tawon yoo si gbe
igbese kiakia. Gbogbo awon owo osu, to fi mo ajemonu lawon yoo rii pe o n te
won lowo lakooko.
Dapo bawon oniroyin soro leyin ipade pelu egbe awon osise |
O wa seleri
ile olowo boo ti mo fawon osise to ba ti wole to ba wole bee ni ko ni osi, iya
ati iponju yoo dopin ninu igbe aye awon osise naa.
Ninu oro Akimu Ambali, to je alaga awon osise
nipinle Ogun, o ni inu oun dun bi oludije gomina naa se sabewo sodo awon, o wa
gbadura pe ti Olorun ba so pe oun ni yoo mu iderun bawon osise ti nnkan yoo fi
dara fun won yoo wole.
Sugbon to ba
je idakeji e naa ni, Olorun yoo se iyanu. O wa gboriyin fun Dapo Abiodun, gege
bi akoni okunrin, o ni oto ni nnka toun
gbo nipa e tele amo oto ni nnkan toun ba.
O so pe ninu
awon oludije bi meta to ti wa sodo awon Dapo Abiodun ni enikeji to se daadaa,
tawon eeyan nigbagbo ninu e. O ni bo tile je pe awon osise ko ti le so lori eni
tawon yoo mu bayi, amo oludije naa kun oju osuwon.
Awon afoju naa ba Dapo Abiodun soro lojo naa |
O ni awon
yoo se ariyanjiyan laarin gbogbo awon oludije gomina naa nibe lawon yoo ti mo
ibi tawon n lo. Ninu oro Oloye Olusegun Osoba lo ti koko ki awon osise fun
takuntakun ti won ja, o ni won ko ni se lasan
O wa ro awon
egbe naa lati satileyim fun Dapo Abiodun gege bi oludije gomina ninu ibo to n
bo. Lara awon to tun wa nibe lawon agbaagba egbe ninu egbe naa lokunrin ati
lobinrin.
No comments:
Post a Comment