Akowe olupolongo igbimo fidie fegbe oselu APC nipinle Ogun, Tunde Oladunjoye, ti so pe kantankantan oro ti ko ni itumo ni Onarebu Ladi Adebutu tegbe oselu PDP so pe Igbakeji Aare orileede yii, Ojogbon Yemi Osinbajo wa lara awon to bu epo petiroolu lu wahala to n sele ninu egbe PDP nipinle naa.
O ni ko soooto ninu oro naa ati pe
bigba ti okunrin naa ko mo nnkan to n se e mo, to wa fee maa fi atamo we atamo
loun ka oro naa si.
Ninu atejade ti okunrin naa fi sita
nirole yii, lo ti so pe Adebutu ko mo nnkan to n so mo ati pe o ti fee so ara e
di alawada adie. O ni wahala to ti n sele ninu egbe ko to di pe o jade gege bi
oludipo, tabi ti ko ba ye ko lo beeere lowo awon to ti wa ninu egbe naa tele pe
kin ni won pe ni igbimo Nwachukwu ati igba ti won da sile.
O ni awon yii ni yoo fun lesi igba
ti wahala ti wa ninu egbe naa nipinle Ogun, nitori ki i se nnkan to sese sele,
nitori idi eyii, o ni ki okunrin naa farabale, ko ye so isokuso nipa nnkan ti
ko ba mo, nitori ogun to n ja PDP nipinle Ogun, Igbakeji aare ati egbe APC ko
mo nipa e.
No comments:
Post a Comment