Tunde Oladunjoye |
Gege bi a se gbo, lojiji ni wahala
naa be sile nigba tawon omo egbe oselu APM loo siluu naa fun ti ipolongo ibo to
bo lona.
Won ni ko to di pe won de agbegbe
ohun ni won lawon toogi kan ti wa nibe, ti won ko si je kawon APM duro nile, ti
won fi da sibasibo bo won.
Sugbon Ogbeni Tunde Oladunjoye to je
akowe olupolongo fegbe oselu APC nipinle Ogun ti so pe ki won se iwadii lori
isele naa daadaa ki won si fawon towo ba te jofin, nitori egbe APC ko mo
nnkankan nipa e rara.
Ninu atejade kan to fi sita lo ti so
pe oludije gomina fegbe oselu naa to fi mo awon alatileyin won ko si niluu naa
lakooko ti isele naa waye, o lawon ti ba ipolongo awon lo si Yewa South fun
iopolongo alaafia tawon n ba kaakiri.
O ni enikeni to ba so awon po mo
wahala to sele naa kan se etanu oselu ati pe won so nnkan ti ko sele, won ni ko
si nnkan tegbe awon fee ri gba ninu ki won da ipolongo ru ati pe egbe won ko wa
fawon toogi.
Oladunjoye tun so pe loju ese ti oludije awon to wa ni Ajilete, ni
Gusu Yewa, lakooko ti isele naa gbo nipa nnkan to sele lo ti lo foro naa to komisanna
awon olopaa leti lori foonu, ti onitohun si seleri pe oun yoo ran awon omoose
oun lo lati lo pese abo.
Bee lo tun so di mimo pe se lawon
toogi tun dena de awon ni lana an, Tosidee, ni Iwoye nibi ti won ti sa okan
lara awon omo eyin won ni ada lori, O lawon ro awon alaabo ilu lati sawari awon
to wa nidi isele laburu naa, ki won si fi won jofin.
O ni lori bi ibo yoo se lo nirowo
rose lo je awon logun, ki i lati maa ta eje awon eeyan sile nipinle Ogun.
No comments:
Post a Comment