Oba Aladetoyinbo Ogunlade Aladelusi, Deji tiluu Akure, to tun je olori oba ni Akure ti so pe oludije aare labe egbe oselu PDP, Atiku Abubakar, nikan lo le ja fun iwa ibaje lorileede yii.
Lojo Aje, Monde, ni Oba naa soro yii
lakooko to n gba alejo oludije aare ohun atawon eeyan e ni aafin e to wa niluu
Akure.
Gege bo se wi, o ni oun ti gbo
gbogbo nnkan nipa Atiku to je gege bi alaseyori onisowo. Bee lo ni oun tun gbo
pe o wa lara awon ti won da ajo to n gbogun tiwa ibaje iyen EFCC sile, eyi to so pe o tumo si pe yoo mo nipa bi won se n gbogun tiwa ibaje ni
Naijiria.
O ni eeyan ko le maa huwa ibaje, ko
tun wa so pe oun yoo da ibi ti won yoo ti maa gbogun tiwa ibaje sile.
Bee loba naa tun salaye pe pelu
iriri ti Atiku ti ni gege bi igbakeji aare, yoo fun ni ona lati sakoso ijoba
laiwo eyin wo.
O ni "Iru eeyan taa n fe
lorileede yii niyii ti yoo le ran wa lowo lakooko ti oro aje wa n lo sile. Gege
bi oba alaye, a ko gbodo gbe leyin enikan, sugbon gbogbo eyi ti mo n so yii je
awon nnkan ti mo gbo nipa e tawon omo Naijiria ba le dibo fun un.
Ninu oro Atiku, o bu enu ate lu egbe
oselu APC nitori bi won se kuna ti won ko mu ileri won se, eyi to je ki Naijiria
wa ninu iponju ati osi lagbaye.
O ni awon naa mo pe awon ko se
daadaa to idi niyii ti won ko fi le jade bo se ye lati polongo, o ni won ko ni
wa sodo oba bawon se wa yii.
O tun wa so pelu idaniloju pe awon
yoo rii pe ida ogoji ninu isejoba won yoo nii se pelu odo.
Lara awon to tele Atiku lo ni Uche
Secondus to je alaga egbe naa, Otunba Gbenga Daniel, to je igbakeji alaga
olupolongo nile gusu. Senato Bode Olajumoke, Lyel Imoke, Eddy Olafeso,
Olagunsoye Oyinlola, Otunba Fasawe, Agbejoro Eyitayo Jegede atawon yooku..
![]() |
|||||
|
|||||
No comments:
Post a Comment