Omooba Dapo Abiodun, oludije gomina
fun ipo gomina labe egbe oselu APC, nipinle Ogun, ti ba awon awon abode ologun
sajoyo iranti awon ti won ti ku soju ogun, eyi ti won maa n se lodoodun, to
waye lodun yii.
Ninu atejade ti Onarebu Remmy
Hazzan, agbenuso fun oludije naa fi sita niluu Abeokuta loni in, lo ti darapo
mo awon omo orileede yii lati ki awon oloogun fun iranti awon ti won ti sun
soju ogun.
O ni oun naa bawon fola fun awon
akoni lokunrin ati lobinrin ti won je ologun, sugbon ti won ti ba ogun lo lakooko
ti won sin ile baba won, pelu igboya ati ifokansin tooto.
O lawon eeyan naa ni won ti femi won
lele lati le je ki a wa ni alaafia, o wa gbadura pe ki Olorun forunke won,
kawon ise ti won ti se lakooko ti won foju winna, ko ma se ja sasan.
O wa lo akoko naa lati so pe okan
pataki to je ijoba logun ni igbe aye awon ologun lakooko ti won wa lenu ise
tabi ti won ti feyinti, ko ye ki won maa fi dun won. O ni inu oun pe ijoba
Mohammadu Buhari to wa lode yii n se.
Oludije naa wa seleri pe bi won ba
fi le dibo yan oun gege bi gomina nipinle Ogun ninu ibo to n bo yii, ijoba oun
yoo sa gbogbo agbara lati rii pe won mu igbe irorun bawon abode ologun atawon
osise abo yooku, awon ko ni gbeyin lati maa se ohun to to fun won lakooko ti
won ba n fe.
*
No comments:
Post a Comment