O tan; Won ni ajo INEC ko gba oruko awon eeyan Amosun wole fun ibo to n bo. - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Wednesday 6 February 2019

O tan; Won ni ajo INEC ko gba oruko awon eeyan Amosun wole fun ibo to n bo.


 
T
Akowe ipolongo fegbe oselu APC nipinle Ogun, Tunde Oladunjoye ti ro awon araalu paapaa julo awon omo egbe oselu lati ma se gba iro tawon ti won jo je alatako ninu egbe naa pa kaakiri pe ajo eleto idibo iyen INEC ti da oruko awon asoju ti won yoo lo eyi ti alaga fidihe egbe naa Oloye Yemi Sanusi pada, won si ti gba ti Derin Adebiyi to je alaga egbe naa tele wole, o ni iro ti jinna soooto ni.


Ninu atejade ti okunrin naa fi sowo si wa lale Ojoruu,Wesidee,
 lo ti ni aheso oro pata ni, nitori funra ajo eleto idibo ni won ko leta sawon pe kawon foruko awon asoju ranse, tawon si se bee loju ese ni won si ti gbaa wole.

O ni eni to ba n paro lo maa so pe eleri oun wa lorun, o ni oun pea won igun keji ti won jo n fa oro naa nija pe ki won gbe leta ti ajo INEC ko si won sita faraye ri. O ni iro ti ko lese nile nile ni ati pea won eeyan funra won gan an le wadii lati mo eni to ba n paro.

Bee lo tun so pe ki i se ayederu oruko ti won fi ranse nikan ni ajo naa ko gba, o ni won ko tun gba leta ti Derin Adebiyi atawon eeyan e ti won tu ka mu dani eyi ti won fi pe egbe lapapo lejo, to wa nile ejo giga apapo kewaa, ti won pe lose to koja sugbon ti won ti sun un di ojo kokanla, osu keta, odun yii.

Oladunjoye ni bile ejo se sun igbejo naa ti fihan pe o digba ti won ba pari gbogbo ibo to wa niwaju, eyi to tumo si pe awon kiatika ni yoo sakoso eto ibo nipinle Ogun.

No comments:

Post a Comment

Pages