Mo fee je asoju rere fawon eeyan mi lati maa ja fetoo won- Wale Oguntade - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Wednesday 6 February 2019

Mo fee je asoju rere fawon eeyan mi lati maa ja fetoo won- Wale Oguntade



Wale Saheed Oguntade
 Okan lara awon odo to n ja raburabu lati je asoju rere fawon eeyan e ni Wale Oguntade, to n dije fun omo ile igbimo asofin nipinle Ogun labe egbe oselu ADC, Abeokuta South kin in ni ni okunrin naa fee soju fun un. Laipe yii lo ba oniroyin wa soro nipa erongba e lati loo soju awon eeyan e, ohun to ba wa so niyii.

Oruko mi ni Onimo-ero Adewale Saheed Oguntade, mo n dije fun omo ile igbimo asofin agbegbe Abeokuta South, kin in ni, labe egbe oselu ADC, nipinle Ogun.

Bi a ba ni ka woo, nnkan to mu wa jade, ko koja pe a ti se ipinnu, a si ni nnkan to wa niwaju wa to je pe a fee se fawon omo ipinle Ogun lati ibere pepe, eyi ti mo si n so naa, boya ka koko loo soju awon eeyan wa nile igbimo asofin lati ja fetoo won.Awon nnkan to ku die kaato, ka bawon se, ka soju won rere.

Bi a ba wo lopo igba awon to maa n se ijoba, won je awon to je pe yala won le maa mo nnkan ti won n se,tabi ki eto ijoba yen maa ye won,a maa rii pe gbogbo awon to n soju wa yii na, awon ti ko kun oju osuwon, ti ko ye ko je, iyen lo faa, temi fi ro pe o ye ki n jade lati dije.Ka le mu igbe aye rorun fawon eeyan.

Ohun ti mo ni fawon eeyan mi

Mo ti so moro leekan pe mo maa je asoju rere lati ja feto won, ona wo leeyan gba n ja fetoo awon eeyan e, ijoba to ba wa nita, a fee se titi, won a fee se omi, won a fee se orisirisi ohun meremere fawon araalu

Beeyan ba maa je asoju rere, waa lo lati maa beeere eto awon eeyan tie, ti won ba ko sinu iwe isuna pe won fee se titi mewaa lodun yen, bawo lo se maa beeere titi todo tie to maa pelu.

Gege bi a se mo pe ise asofin, wa nile igbimo asofin, awon ofin kan wa to je pe awa ti maa n wo lopo igba pe o ku die kaaato. Bi onimo ero mo rii pe lati bi odun marun un sigba ta wa yii, ko si awon onise owo, to ka oju osuwon to bi awon omo ile Kotonu, Togo lo poju ninu awon onise owo,eyi tumo si pe  imo ero amodoju, tabi dogbon owo ka fi yi nnkan da, a ti sonu nipinle wa.

Lara awon nnkan ti mo fee loo se ni kaa ri pe a da awon imo gbogbonse yen pada debi pe awon omo to maa kose, won a le we yan kainkain lati mo nipa ise owo won.

Mo tun sakiyesi pe iya to n je awon obinrin wa ti poju,won n pe kin ni kan ni komu le lanta, ni nnkan bi odun mewaa seyin,, o wa sugbon kog gbajumo to bayii. Bi a ba le gbiyanju lati se awon ofin kan ati wi pe ka sawon awon eto kan lati le mu igbe aye irorun bawon obinrin.

Awon eto bi eyawo ti ko ni gara, ti ko si ni ni ele ninu.Awon komu le lanta yii, owo ele ti won n san ti poju. Ati pe awon odo wa, bi mo se wa yii, ka bawon odo wase je nnkan to je mi logun gan. Gege bi mo se n sise ati gbogbo ise mi ni Abeokuta yii, Olorun ke mi pe mo ba baba wa Obasanjo sise. 
Mo ti wa pelu won tipe. Eyi fun mi laaye, bi ko ba le nigba odo ti mo ti gba sise nigboro ilu Abeokuta yii. Bi a se maa se ti a maa wa ona lati gba odo wa sise iyen naa pelu awon nnkan ta maa se.

Abo awon eeyan mi je mi logun

Bi a ba n soro eto abo, ise to po ni, opo igba awon odo la maa n ba ni iru awon iwa bii jagidijagan, oun la se so pe a maa gbiyanju, se e ri ise tawa fee se, o wonu ara won, oga wa, to n dije fun gomina, Gboyega Nasir Isiaka gege bo se maa n so pe ijoba tiwa ki I se gbogbo e la maa se, nitori a ko le se gbogbo e tan.

Sugbon iwonba taa ba mu nibe, ni tie, o mu meje, ninu e naa lawa naa duro si abe, bee ba ri gbogbo e, e o rii pe o wonu ara won. Bi onikaluku ba n loo sibi ise e, ti ko si wahala, e o rii pe eto abo yoo ni itumo laarin ilu.Eyi mo koko ri nibe ni pe ka fopin si ebi, ise ati iponju laarin ilu, nitori owo to ba dile ni esu bee wo.

Iriri mi nidi oselu

Bo tile je pe odo ni mi, mo ti bere oselu tipe, nitori eleeketa ti mo maa gbe apoti oselu ree, ni odun 2014, mo tiraka lati dije fun omo ile igbimo asofin ninu egbe PDP, sugbon o ku ose kan ki won se ibo abele, lawon agba egbe pe mi pe ki n loo duro fun eeyan kan lati lo to ba digba mii in o maa kan mi. Mo gbo si won lenu.

Ni 2016, lawon agba yii tun ni ki n jade lati dije fun alaga ijoba ibile ni Abeokuta South, a gbiyanju nigba naa, taa si mo pe a wole, amo bi e se mo pe ibo ijoba ibile, ipinle lo maa n se amojuto e, won se bi won yoo se e se, a si gba kamu.

Odun 2017, nigba ti idajo wa lati ile ejo lati oke wi pe awon kan lo ni egbe, ti won si ni awon to n soju egbe, ki won da won nu, won yan mi gege bi alaga ijoba fidihe fegbe PDP ni Abeokuta South. Osu meta ni mo se, ti mo si gbiyanju. Awon tie de wa ye ara wa la jo kuro ninu egbr PDP bo si ADC ti mo ti jade bayii.

Gbogbo awon ta jo dije ni Abeokuta South ko ba mi leru

Ko seni ti ko koju osuwon niwonba tie, sugbon nnkan ti mo maa so niyii, egbe oselu APC, awon eeyan ti ri won gege bu opuro, apuro ta tawon araalu ko fee gboro won mo, bo ti wu ki eni to jade nibe se le niwa to, awon eeyan yoo si maa ro tegbe.

Ninu egbe APM, eni to n to n dijr fun ipo gomina labe egbe ADC naa ti rin irinajo bee ri, to lo latinu egbe PDP lo si PPN, ofo lomi efo se naa ni.ko si nnkan ti won ba bo, iru e ki I je bigba ti won ti gbesi idanwo ni. Gege bi oloselu toro ye, ko seni ti a ko danu ninu won, gbogbo won naa lo maa ribo amo sa, emi lo maa bori.








No comments:

Post a Comment

Pages