Awon odo Ogun Central so pe Segun Sowumi lawon yoo dibo asoju-sofin fun un - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Wednesday 6 February 2019

Awon odo Ogun Central so pe Segun Sowumi lawon yoo dibo asoju-sofin fun unSegun Sowumi
 Awon egbe odo ti Ogun Central ti so pe ko si awitunwi asan kankan Segun Sowumi, to je oludije fun ipo asoju-sofin ni agbegbe Abeokuta South labe egbe oselu PDP nipinle Ogun lawon gba lati sise fun un, ko le baa wole ninu ibo to n bo lojo kerindinlogun, osu yii.
 Ninu oro ti Ogbeni Kehinde Solola to je alakoso egbe naa nipinle Ogun so lo ti so pe ise awon odo naa ni lati mu enikan soso tawon yoo jo gbimo po sise fun ipo asoju-sofin niluu, idi niyii tawon fi mu Sowumi nitori awon mo pe oun nikan soso lo koju osuwon ninu gbogbo awon to jade lati ekun naa.


O tun salaye pe idi tawon fi mu okunrin to tun je agbenuso fun Atiku fun ibo aare to n bo naa ni pe o je akikanju eeyan to nifee  lati mu idagbasoke ba awon eeyan agbegbe to fee soju fun.
O tun salaye pe akoko ti to fawon odo lati dibo yan eni to koju osuwon, to kawe, to ni iriri, to si tun ni ife araalu lati soju awon eeyan, ki ohun rere le te won lowo, eni tawon si mo pe o le se iru e ni Segun Sowumi, ti won lo ti pe ninu oselu.
Won ni bi okunrin yii ba fi le di asoju-sofin, o da awon loju pe gbogbo ohun idagbasoke ni yoo mu ba won bee ni yoo tun le sagbekale awon abadofin ti yoo mu irorun bawon omo ipinle Ogun.
O ni okunrin to maa kopa nipa oro oselu yoo se daadaa lati rii pe eto awon eeyan e tee lowo nigba to ba depo naa. Won wa ro gbogbo awon olugbe Abeokuta South, to fi mo awon oba atawon ijoye lati satileyin fun okunrin naa, ki erongba e lati so agbegbe naa dotun, ko le di mimu se.

No comments:

Post a Comment

Pages