Doyin Ogunbiyi |
Arabinrin Doyinsola Ogunbiyi to ti
figba kan je komisanna nigba meta otooto nipinle Ogun ti tan imole lori bi won
se da ohun awon obinrin ipinle Ogun sile gege bi ipenija ilosowaju ati
idagbasoke eto awon obinrin.
Gege bo se so o ni egbe naa je tomo
bibi obinrin ipinle Ogun tabi to fee won nipinle naa, o ni awon fee je ki egbe
naa tan gbooro kaakiri lati le je kawon eeyan mo won.
Obinrin naa to tun je Diakoni tun
salaye pe awon wa fun lati maa ja fetoo gbogbo awon nnkan to ba je tobinrin ati
pe awon ki i eni ti won le ma foju pare
lawujo.
Bee lo tun salaye pe awon yoo rii pe
ilosiwaju ati idagbasoke de bawon obinrin
ati lati je ki won mo pe awon obinrin maan mu eso rere jade nipa erongba
ati mu aseyori ba ipinle naa.
O tun so pe awon obinrin naa ni
anfaani lati kopa ninu gbogbo isejoba lati le saseyori eleyii won gbodo maa
fawon obinrin ni ida ogoji ninu ipo isejoba.
Bee ni egbe ohun awon obinrin tun
fee ki itoju de ba awon molebi lori awon nnkan wonyii bii ile gbigbe, eto eko
to yanju, riro awon obinrin lagbara nipa eto eyawo fawon oloja atawon olokoowo
lati maa fi satileyin fun won.
Gbogbo eru nipa sisan owo ori lo so
pe won gbodo mu kuro ati pe won gbodo maa bowo fawon obinrin ki won maa foju
kere won nipa oselu.
Nipa to n soro nipa erongba egbe
naa, Doyin Ogunbiyi salaye pe lara e ni
lati maa je kawon obinrin maa raye lati maa soro sita nipa nnkan to n ba sele
lawujo ati ijoba.
Lati fi emi igboya sawon obinrin
lokan tun je erongba won lati je ki won pataki aye won. Bee ni polongo awon obinrin lati mo nnkan ti won wo
lawujo.
Bee
lo ni awon yoo tun je kawon obinrin mo ohun ti agbara won gbe ati pe idanilekoo yoo maa wa
loorekoore lori eto won, ki won si nimo awon anfaani to wa nibe.
Lori awon ise to wa niwaju won ,
obinrin naa so pe awon ti setan lati gbe so igbe aye awon obinrin di otun. Lati
maa wo awon obinrin gege bi awokose rere ni orileeede gbogbo agbaye.
O wa lo akoko naa fun ifowosowopo
awon eeyan paapaa fun ipolongo egbe naa lati le saseyori awon erongba won fun
egbe naa
Bee la gbo pe Arabinrin Olufunke
Fadugba ni alaga egbe naa, won tun wa bebe fun atileyin lati gbe egbe ohun awon
obinrin ipinle Ogun dide.
No comments:
Post a Comment