Dapo Abiodun |
Remmy Hazzan, agbenuso fun oludije
gomina labe egbe oselu APC nipinle Ogun, iyen Dapo Abiodun ti so pe ko si ooto
kankan ninu aheso oro tawon kan gbe jade pe oludije naa fawon Ogun West, iyen
Yewa se yeye lakooko to n se ipologo ibo.
Ninu atejade ti okunrin naa fi sita
lo ti salaye pe awon to n so isokuso naa fee fi da wahala sile ni, nitori Dapo
Abiodun ko le fenikeni se yeye.
O ni iyalenu lo je fawon abinu eni
naa se n paro fawon eeyan kaakiri leyin aseyori ipolongo ti won se pelu
igbakeji aare orileede yii ti won si n so nnkan ti ko sele lati fi ba nnkan je.
O so pe awon pe awon obayeje naa nija
lati so ibi, akoko ati igba ti Abiodun yeye awon Yewa lakooko to n soro, o ni
awon mo pe iroyin eke ni, ko si le tu iru kankan lara awon nigba tawon mo pe ko
si nnkan ti ko le sele ti iplonogo ibo ba n loo lowo.
Agbenuso fun oludije naa so pe dun
fawon agbaagba atawon omo egbe naa kaakiri ipinle Ogun pe won mo pe iru oro bee
ko le jade lenu oludije won, nitori won mo pe ko le fenikeni se yeye.
O ni ipolongo tawon n se lowo lawon
dojuko ko si saaye fawon iroyin eleje to le mu ifaseyin bawon, o ni iru awon to
n so isokuso bee atawon to n ran won ko ba
kuku maa se ipolopngo won lo dipo lati maa paro fawon araalu eyi to le
da wahala sile nipinle Ogun.
O ni pelu odun metalelogoji tipinle
Ogun ti pe ko ye ko si aye awon oloselu ti won ko mo nnkan ti won se ju ki won
maa paro lo mo.
O wa ro awon alatako oselu nipinle
naa ki won yera lati maa sagbekale awon iroyin ti ko je ooto ki won si gba fun Olorun
lori bi gbogbo awon eeyan se satileyin fun Dapo Abiodun fun ibo to n bo naa.
Bee ni won tun ro araalu lati ma se
gba awon iroyin ti ko je ooto naa gbo nitori gbogbo omo awon ipinle Ogun ni
Dapo Abiodun bowo ko se le so aida oro senikeni.
No comments:
Post a Comment