Nitori esun ikowoje; Won fee fi ajo EFCC mu Onarebu Mikky Kazem - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday 8 February 2019

Nitori esun ikowoje; Won fee fi ajo EFCC mu Onarebu Mikky Kazem


 
mikky Kazzem

Bi nnkan se n loo yii, afaimo ki Onarebu Mikhail Kazzem tawon tie n pe ni Mikky, to n soju ekun Abeokuta North, Odeda ati Obafemi Owode nile igbimo asoju-sofin niluu Abuja labe egbe oselu APC sugbon to ti darapo mo APM bayii maa wonu wahala nla nitori bawon kan se ko leta ehonu sajo to n ri si iwa ibaje ati sise owo ilu basubasu iyen EFCC lori esun ikowoje,  ninawo ijoba ni inakuna.

Ninu leta kan tawon egbe kan to pe ara won ni Ogun Collective fowo si, eyi ti won fi ranse si wa ni won ti salaye bi okunrin to tun fee dije fun ipo asoju-sofin labe egbe oselu APM se da awon owo to ye ko fi sise akanse sona ibo mii in, eyi ti won so pe o lodi sofin.

Won so di mi mon pe laarin odun meta laarin odun meta seyin to ti wa nibe lawon ti sakiyesi ona ti Mikky n gba n nawo awon owo ti eto isuna ti la sile fawon ise akanse si apo ara e nigba tawon to wa to wa labe e ko si jere kankan.

Won ni ere ijoba tiwantiwa ni pe kawon to soju won niluu Abuja  sise tawon araalu yoo janfaani nibe nigba ti won ba gbaa wole sugbon kaka ki asoju awon yii se be, apo ara e ni won so pe o n ko si.

Won wa ro ajo EFCC lati lo ofiisi won lati se iwadii lori esun tawon fi kan Mikky Kazzem naa bere lati odun 2016 titi di odun 2018, awon ise akanse to so pe oun fee se amo ti ko se, to si gbowo e sapo.

Lara awon alaye ti won tun se lati fidi oro won mule ni eyi ti won pe ni 1484 eyi ti won so pe o nii se lati tun awon ileewe kan se bii Ajuba village Secondary School, Odeda LGA2, Community High School, Abaren Ofada, Obafemi Owode ati Ansar Ud deen pry School, Oke- Ido, Abeokuta North, milionu lona aadota ni won so pe o gba sugbon ti ko se nnkankan.

Atawon bee bee lo ni won ko fi sowo si ajo EFCC lati se iwadii lee lori. Awon ti won fowo siwe naa ni Johnson Akin Soyinka lati ijoba ibile Odeda. Olu Ayinde, lati Abeokuta North, Wale Atanda lati ijoba ibile Obafemi/ Owode ati Funmi Akinwale toun naa wa lati Abeokua North.

Sugbon Onarebu Mikky Kazeem ti won fesun kan ti so pe ko si ooto kankan ninu esun ti won fi kan oun, o ni ki won loo kaakiri awon agbegbe to n soju fun, ti won ko ba ri awon ise akanse toun se.

Bee lo tun so pe lodun 2018 ko sise kankan tawon se titi di oni yii, nitori awon ko rowo gba. 


Eyi ni  iwe akosile awon ise akanse ti won ni Onarebu naa ko se tiwon ranse si ajo EFCC.

 

No comments:

Post a Comment

Pages