Nitori Dapo Abiodun; Won ni Amosun fee wo ile Adajo agba Ilori l' Abeokuta - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Saturday 9 February 2019

Nitori Dapo Abiodun; Won ni Amosun fee wo ile Adajo agba Ilori l' Abeokuta


Ile Adajo agba Ilori ti won ni won fee wo

  Titi di akoko taa n soro yii, inu iberubojo lawon ebi Adajo agba tele nipinle Ogun, Iyen Oloogbe Adajo Ilori was bayii nitori bi won se bi won fee tori oselu wole baba naa to wa ni Adatan niluu Abeokuta 

Gege bi a se gbo, losan ojo Eti, Fraide, ana an lawon kan sadeede de iwaju ile naa lati fi ami sii fun imurasile lati wa wo ile naa.

Bawon eeyan to n gbe laduugbo naa se ri won ni won ti tu jade pe ki lo sele, bo tile je pe awon eeyan naa ko soro ju pe won kan waa woo lati fami sii

Bi Iyawo baba naa, toun ti pe eni odun metadinlogorin, Alaaja Mobolaji Ilori ti se ri won ni okan e ko to bale, to si n rawo ebe pe ki won ma wa wo ile naa.

Sugbon iwadii fi ye wa pe oro naa fee lowo oselu ninu, won so pe nitori pe awon Amosun rii pe ti Dapo Abiodun to je oludije gomina labe egbe oselu APC lawon ebi baba Adajo agba naa n se ati pe won ko fi boo, won tun gbe aworan oloselu naa sibe ni won so pe gomina naa se pinnu lati wo.



Ninu oro Iyawo Baba Adajo agba naa, ebe lo n be awon araalu ki won ba oun be Amosun, ko ma se was wole awon.

O salaye pe lakooko kan, won to wa wo iwaju odo awon, ti won lawon fee fi se titi, tawon ko si bawon fa wahala sugbon ki i se pe ile awon tun sunmo titi, o kan fee fi se etanu oselu..

Mama kan naa toun ti le ni ogorin odun, Iyaafin Aderayo Akinsola to nile ile ti won fi ko ile-epo to wa legbe ile Adajo Ilori ti won tun fee wo odo ti won naa so pe iya ni Amosun fee fi je oun yii nitori awon to wa lori ile naa, o tipe ati pe awon lawon ta fawon to fi kole epo.

O ni ireje loro naa fee je fun awon. Lara awon to wa lagbegbe naa to ba wa soro so pe oselu ni won fee ki bo oro yii ati pe ko sese maa sele.


Asiri ti won lo si wa nidii oro naa ni pe awon ti Ilori ko se to Gomina, won lo si ti wa ninu iwa Amosun pe gbogbo awon ti ko ba se tie ninu oselu lo maa n kanra mo, won nitori e lo se fee wo ile Baba naa to to fi opo odun wa nibe.

Sugbon titi di akoko taa n ko iroyin yii lowo, ko tii seni to le so ibi ti oro naa maa ja si, ebe tawon araadugbo n be ijoba Amosun ni pe ko maa fi ojo kekere to ku ti yoo lo lori ipo to wa ba nnkan je.

https://ssl.gstatic.com/ui/v1/icons/mail/no_photo.png


No comments:

Post a Comment

Pages