Lati apa osi, Oloye Mary Ogunjobi, Oloye Ayo Oyegbola ati Ojogbon Anthony Asiwaju nibi ayeye naa |
Lojo Abameta, Satide, ose to koja yii lawon
agbaagba, olori elesin atawon eeyan lawujo to fi mo awon osise feyinti nile
Yewa ko ara won jo niluu Ilaro ti won fimo sokan pe oludije gomina fegbe oselu
ADC, Gboyega Nasir Isiaka, GNI lawon yoo dibo fun ipo gomina to n bo lojo keji,
osu keta odun yii.
Nibi apero kan ti alabasisepo Ogun
West se ni won ti fenu ko pe niwongba tegbe oselu APC ti ja won kule lati fa
oludije to wa lati Yewa Awori kale lawon se panupo lati sise po pelu GNI to wa
latinu egbe ADC, toun naa je omo bibi ilu won.
Ninu oro Dokita Kunle Salako to je
alakoso egbe naa so nigba to n ki awon eeyan kaabo sibi eto to waye ohun, O so
pe lakooko yii, ipin sipo inu egbe oselu APC ti mu ijakule bawon ni Ogun West,
idi niyii tawon fi tete gbe igbese tawon gbe tawon fi gba lati sise po pelu
oludije mii in labe egbe oselu ADC.
O tun so pe leyin gbogbo agbeyewo
tawon se pelu awon oludije marun un to ku, tegbe oselu mii in fa kale lawon ti
rii pe ko selomii in to tun koju osuwon bi ko se GNI.
Awon ero repete nibi ayeye naa |
Lara awon to wa nibe lojo naa ni Asiwaju gbogbo ile Awori Senato Ayo Otegbola, Asiwaju ile
Yewa, Ojogbon Anthony Asiwaju, Ekerin tiluu Ota, Oloye Bamgboye Osunlabu, Otunba
ilu Ilaro, Dokita Samuel Ibikunle, Iyaloja ile Yewa, Oloye Arabiinrin Yemisi
Abass.
Awon yooku tun ni
Ambasedo Ebun Oyagbola, Alhaja Salimotu Badru, Oloye Iyabode Apampa,
Oloye Bisiriyu Popoola, Onarebu Lai Taiwo ati Oloye Mary Ogunjobi atawon
mii in.
A o ranti pe lati
nnkan bii odun metalelogoji seyin ni awon omo Yewa Awori ko ti ni enikankan to
ti odo won wa di gomina nipinle Ogun. Leyin ti Egba ti je leemeji ti Ijebu naa
ti je leemeji.
Nigba toun naa soro
nibi ayeye naa, Omooba Gboyega Isiaka dupe lowo gbogbo awon eeyan naa fun ife
ti won ni soun ti won fi gba lati dibo foun gege bi gomina lodun to n bo.
O wa ro awon eeyan ile
Yewa lati lo anfaani ti won foun lati dibo yan an oun wole, lati tan an ka
gbogbo ile Yewa, o ni ko buru ju toun ba mu ida aadorin ninu ogorun un ninu ibo
naa lati odo won wa.
No comments:
Post a Comment