Dapo Abiodun |
Oludije fun ipo gomina labe egbe
oselu APC, Omooba Dapo Abiodun ti seleri pe oun yoo mu eto eko ati igbe aye
irorun fawon akekoo toun ba fi le wole gomina ninu ibo to n bo naa.
O salaye oro yii lakooko to n bawon
omoleewe ikose ilera iyen College of Health Technology to wa ni Ilese- Ijebu
soro fun ti ipolongo lati dibo yan an wole gege bi gomina, eyi to sese bere
loni in.
Se lawon akekoo naa tu jade lati wa
pade e pelu ileri pe ko fokanbale, oun lawon yoo dibo to n bo ninu osu keta naa
fun.
Oludije gomina naa wa fokan won bale
pe gbogbo nnkan to ba to to si ye lati mu ki eto eko rorun loun yoo se,
niwongba ti won ba to sebura foun lojo kokandinlogbon osu karun un odun
yii.
Bee lo tum seleri lati satunse lori
awon ona to won ileewe naa, bee lo ni oun you tun bawon ri si eko off iyen
scholaship ati ibi to won ti n kawe, library won, ati owo ti won maa n fawon
akekoo.
Ipolongo ibo gomina ti Dapo Abiodun
bere lo ti lo si Atan nijoba ibile Ijebu North East nibi tawon araalu ti wa
pade e, ti won si n seleri fun Abiodun pe ko maa mikan, oun lawon yoo dibo fun.
Oun ati igbakeji e, Noimot
Salako-Oyedele naa ni won jo rin irinajo naa, nibe lo ti mu dawon eeyan agbegbe
naa loju lati sejoba to dara, si satunse awon ona, riro awon obinrin ati odo
lagbara ati ipese eto ilera to ba ode oni mu
No comments:
Post a Comment