Awon ara Abeokuta South ni Segun Williams fakoko e sofo ni, ko sibi to n lo. - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Monday 7 January 2019

Awon ara Abeokuta South ni Segun Williams fakoko e sofo ni, ko sibi to n lo.



Segun Williams
 Latigba tawon olugbe Abeokuta South ti gbo pe Onarebu Segun Williams to n soju won nile igbimo asoju – sofin niluu Abuja ti n mura lati dije eleeketa lawon eeyan naa ti soko oro ranse sii pe ki lo tun wa ati pe kin ni nnkan to se laaarin odun mejo to ti wa nibe.

Bo tile je ninu egbe oselu APC nipinle Ogun ni Olorun ti fun un ni oore ofe lati soju awon eeyan e niluu Abuja sugbon bayii, egbe oselu Labour lokunrin naa ti fee jade bayii, eyi to je kawon eeyan  fi n se yeye pe nigba ti ko rowo mu ninu egbe to wa tele lo se loo sinu egbe tuntun toro awon naa ko tii ye ara won titi di akoko yii.

Gege bawon olugbe naa ti wi, won lawon n fee oludije mii in ti yoo gbo nnkan tawon n wi, tawon naa yoo si maa gbo tie, ti ko ni dabi eni to wa nibe bayii, to je pe akoko to ba fee kawon dibo fun un lo maa n yoju.

Igba akoko ko ree ti won so pe yoo ma huwa yii, won nigba to fi se asoju awon niluu Abuja, bo se se naa niyi tawon ko fee ko pada se eleekeji, bikose Gomina Ibikunle Amosun to baa bebe.

Nigba towo e tun te tikeeti tan, to wole, se ni won lo da awon na nu, won ni awon fee ko wa nawo si ise idagbasoke to se si Abeokuta South latigba to ti wole eleekeji.

A tun gbo pe ka ni okunrin naa se daadaa ni, ko ni kuro ninu egbe APC to wa tele, bo tile je pe wahala wa ninu egbe naa, sibe awon kan si duro, ti won si fun won ni tikeeti.

Gbogbo akitiyan wa lati ba Onarebu Segun Williams soro lori oro yii lo ja si pabo, nitori bi a se gbe ipe e ni ko gbe, igba to si tun gbe, se lo seleri pe oun yoo pe pada ti ko si se bee titi di akoko yii.

Loro kan, awon ara agbegbe Abeokuta South ni yoo soro fun Segun Williams lati wole eleeketa, eyi to jade labe egbe oselu Labour.

No comments:

Post a Comment

Pages