Dapo Abiodun |
Egbe olupolongo fun Dapo Abiodun ti
pariwo sita pe awon kan tu n gbero lati maa da ipolongo oludije fun ipo gomina
labe egbe oselu APC nipinle Ogun, Dapo Abiodun, won lawon eeyan naa ko moro naa
ni kekere.
Ninu atejade ti agbenuso fun oludije
gomina naa, Remmy Hassan fi sita lojo Aiku, Sannde, lo ti so pe gbogbo ona ni
won fee maa gba lati doju ija ko won ti iponlongo ba n lo lowo.
Okunrin naa tun salaye pe bawon se n
pinnu lati bere ipolongo awon lati ijoba ibile Ijebu North East lojo Aje Monde,
o se pataki
lati so fawon araalu pe awon ti gbo
pe pelu aridaju pe awon kan ti n gbimo lati dena de awon pelu idojuko awon moto
to ba tele Dapo Abiodun.
Remmy Hassan tun so pe“A fee ki awon
araalu mo pe igbimo ipolongo Dapo Abiodun ti seleri tele ko ni si wahala kankan
lakooko ipolongo. Sugbon a ti gbo pe awon oloselu kan yi n satileyin fawon
toogi lati da wahala sile lati le fi so lenu lakooko ipolongo to fee bere you.
Agbenuso fun Dapo Abiodun naa tun
fikun oro e pe gbogbo bawon se fee rin fun ipolongo awon ti fi sowo si awon
eleto abo,awon ki fee safojudi sawon to fee dibo kankan been lo ni awon yoo yun
tesiwaju lati maa ba awon eeyan soro lati je ki won mo iran gidi ti Dapo
Abiodun ni fun won laiberu enikeni.
O ni bakan naa lawon gbo pe ijoba
ipinle Ogun to n gbe igbese lati tu igbimo awon alakoso kan ka nijoba ibile
nipinle Ogun tawon alaga atawon kanselo won ti yari pe awon ki le fegbe APC
sile, ti won si tun ko lati side tako egbe naa.
O ni bi ose meloo kan seyim bayii
lawon omo egbe won ti n koju orisirisi idojuko. O wa ro won eleto abo nipinle
Ogun lati tete bere si nii gbe igbese lati ma je kawon kan tori oselu ba ipinle
yii je.
|
|||||
|
|||||
No comments:
Post a Comment