Salvador |
Adari ipolongo fun Buhari/Osinbajo nibi ibo aare nipinle Eko, Onarebu Moshood Salvador tun ti so pelu idaniloju Aare Muhammadu Buhari yoo feyin Atiku gbole ninu ibo to n bo losu keji odun yii.
Lojo Abameta, Satide, ana an, lokunrin
naa soro yii lakooko to n ba awon omo egbe APC soro nibi ayeye ita gbangba ti
won se laduugbo Maryland, niluu Eko. O so pe ibo ile Hausa ati tile Yoruba ti
foun lokanbale pe alubami ni Buhari yoo lu Atiku.
O tun tun un so lojo naa pe ipolongo
Atiku to n dije labe egbe oselu PDP nipa atunto ko mu itumo kankan dani, o kan
fee fi ri ibo ko ni.
Salvador salaye pe egbe oselu PDP ko lagbara lati seru eto bee,
o ni iru nnkan bee ki i se ohun ti eya kan le da se, ati pe ko le seese ninu
oselu ta n ba loo ni orileede yii.
O wa gbogbo awon to fee maa gbona
eto atunto wole sawon eeyan lara, ki won ya tete fopin si.
Okunrin naa tun so pe egbe oselu PDP
mo pe erongba ile gusu ni Naijiria ni. O
ni won si mo pe ona kan ti won le gba wole sawon eeyan lara ni ki won gbe ona
eto atunto naa loo sodo awon agbalagba lati maa so nipa e.
O wa beere lowo awon agbalagba naa
pe kin ni nnkan ti won wo lateyin wa tele?
O ni lara won wa to je pe latigba ti won ti wa lomo odun metadinlogbon
ni won ti wonu oselu ti won si ti pe aadorin odun bayii.O ni kilode ti ko seese
fun won lati satunto latojo yii wa, to wa je pe igba ti won dogbo tan ni won wa
ro pe awon le se?
Bakan naa lo tun seleri pe egbe
oselu APC ni yoo wole ibo gomina ti won fee di ati pe ko tie si nnkan to n je
egbe PDP nipinle Eko.
“O ni latigba toun ti fegbe PDP sile
atawon bii milionu alatileyin oun legbe naa ti ku. O ni ninu ibo gomina to waye
lodun 2015 APC ni ibo 794,000 nigba ti PDP
ni 620,000. Sugbon ni bayii, gbogbo e lo maa yipada ninu ibo to n bo yii nitori
ilopo e ni APC fi maa na PDP.
Ninu oro ti Seneto Anthony Adefuye
nibi ayeye naa, o ro awon omo egbe lati maa se iplongo lati ojule dojule lati
polongo ibo fawon araalu.
|
No comments:
Post a Comment