Ogbeni Biodun Owolabi, Gboyega Nasir Isiaka ati Sunday Oginni nibi ayeye naa |
Se loro gbona mii- in yo
lojo Eti, Furaide, nigba tawon igun kan ninu egbe oselu Labour nipinle Ogun gba
lati dibo won fun Gboyega Nasir Isiaka iyen GNI gege bi gomina fun ibo to n bo
lona.
Ayeye ohun to waye ni
ofiisi egbe naa to wa ni Adatan lawon omo egbe naa ti panupo pe GNI ni oludije
kan soso tawon ni fun ibo gomina naa pelu ileri pe awon yoo sise fun un lati
depo naa.
Bo tile je pe nibi ayeye
naa awon asaaju igun keji iyen Abayomi Arabambi to je alaga won, Bode Simeon
to ti figba kan je alaga egbe naa ko yoju sugbon awon eeyan ko mo pe won ko si
nibi ayeye ohun.
Ninu oro Ogbeni Biodun
Owolabi to je alaga egbe oselu naa ati akowe e,Sunday Oginni ni won ti so pe awon
ti wa lenu pe kawon gba lati dibo fun GNI gege bi oludije won, o ti pe die seyin,
sugbon awon dupe pe gbogbo e yori si rere lakooko yii.
.
Owolabi salaye pe ki I se
pe awon da igbese naa gbe, bi ko se pe gbogbo awon oloye egbe naa lo fowo si
pata ninu ipade won.Bakan naa lo tun ni awon sagbeyewo gbogbo awon oludije
gomina yooku kawon to ri pe GNI kun oju osuwon lati sise fun
Nigba to kin oro alaga e leyin, Sunday Oginni to je akowe egbe
naa so pe gbogbo omo oloye egbe atawon omo egbe lo fowo si igbese tawon gbe naa
lati satileyin fun oludije gomina latinu egbe ADC.
O ni awon mo daju pe oludije kan soso tawon le sise po pelu e ni
GNI. O tun so pe pelu idanimo egbe eyi
to safihan owo meji, o ni eyi tumo si pe ajosepo owo egbe oselu Labour ati ADC lo papo. O wa gba awon eeyan nimoran pe ibi
ti won ba ti ri ami owo meji ni kawon eeyan dibo gomina fun.
Ninu oro ti Gboyega Isiaka o dupe lowo egbe oselu Labour fun
igbese ti won gbe naa lati pe si ipade nibi ti won ti gba lati dibo fun un. O
ni oun gbo pe egbe naa gba lati dibo foun, idi niyii toun fi wa dupe.
No comments:
Post a Comment