Oloye Obasanjo ati Ogbeni Babatunde Gbadamosi |
Nibi irinajo naa ni oludije gomina
naa ti so erongba fun Obasanjo pe oun fee dije fun ipo gomina labe egbe oselu
ADP nipinle Eko, o ni gege bi aare tele naa se je baba, awon wa lati wa gbo oro
imoran ati itosona lenu e.
Ninu oro Obasanjo lojo naa, o so pe
inu oun dun lati gba Gbadamosi atawon eeyan e lalejo ati pe nnkan to se pataki
ni lati koju mo nnkan tab a n se, eyi yoo tun je ki orileede yii tun sun
siwaju.
O tun so pe ko si nnkan ti ko seese
sugbon ohun to se Pataki ni lati jo fowosowopo lati jo saseyori ninu ibo to n
bo lodun 2019. O ni ipongo ibo nii se lati fakooko sile, o war o oludije naa
lati rii pe kan sawon araalu.
Ninu oro alaga egbe naa, Agbejoro Adewale Bolaji dupe
lowo aare orileede tele fun bo se gbawon lalejo,o wa seleri pea won ko nii jinna si lati le maa wa gba
amoran lati enu e.
Lara awon to
tele oludije gomina naa wa ni
igbakeji e,
Arabinrin Habitat Adeosun, alaga
egbe naa,Agbejoro Nasir Adewale Bolaji, Alhaja Yetunde Dosunmu Atobajeun ,
olori awon obinrin ninu egbe naa ati Omooba Adelaja Adeoye to je alukoro egbe
naa.
No comments:
Post a Comment