Onarebu Salvador |
O soro yii
lakooko to n baa won oniroyin kan soro nile e, o so pe gbogbo ariwo ti Atiku n
pa kaakiri ile Yoruba ati Ibo pe toun ba di aare, oun yoo rii pe atunto waye
lorileede yii, o ni oro abe ahon lasan ni, nitori pe to ba fi le de, se ni yoo
tun so pe oun ko ro pe atunto naa le waye, o ni ko si ye kawon araalu je ki okunrin
naa gbe won mora, nitori ko ni nnkan gidi to fee se fun won.
Salvador tun salaye pe Alagba Ayo Adebanjo to ti n tele
Oloye Obafemi Awolowo lati nnkan bi odun metadinlogbon, to ti deni aadorun un odun
bayi, ki lo de to fi je pe akoko yii ni baba naa sese n pariwo eto atunto.
O so pe ‘Atunto
ta n so yii, ara eto awon agbegbe gusu lorileede yii ni, Fun bi odun mejo ti
Obasanjo fi wa nijoba ko soro nipa e, nigba ti Jonathan naa debe oun naa ko
menuba. Bawo lo se wa je pe Yoruba lo jade ti won saaju eto atunto, eyi ti
gbogbo wa si mo pe ko le seese’
O tun fikun
ninu oro e pe ti a ba ni ka sagbeyewo awa ta fee dibo, gege bi ajo INEC se fi
sita,awon to wa lati ile Hausa lo poju ti won je milionu lona ogoji, nigba tawa
Yoruba ati ibo lapapo je milionu mejidinlogbon.
O ni ile
Yoruba ati Ibo nikan ni Atiku ti n
pariwo atunto yii lati mori won mabe, ko polongo e nile Hausa to ti jade wa, o
nitori o mo pe ko nii fowo si.
Salvador tun
so pe Atiku gan-an mo funra e pe oun ko le se atunto, a fi koun maa paro fawon
eeyan wa, bo se n pa yii, nitori ki owo e le te nnkan to ba fe. O ni nigba ti
yoo ba fi to osu mefa ni yoo pariwo sit ape agbara oun ko le gbe, nitori awon
omo ile igbimo asofin,ko tii setan pelu oun. Ara iro tawon oloselu maa n pa lo
n pa yen.
O wa so
gbangba pe orileede yii ko ti setan atunto lakooko yii, o lo wa lara ofin ile
wa, Awolowo lo, bee naa lo ni ijoba ipinle Eko naa n lo. Ipinle meji si meta le
satunto ara won nipase eto oro aje to gbooro,owo yoo si maa wole fun won taara
laiwo oju ijoba apapo.
No comments:
Post a Comment