Egbe oselu
All Progressive Congress, APC tipinle Ogun ti so pe o ye kawon eeyan kaaanu Gomina
Ibikunle Amosun pupo pupo bee awon si tun ni lati gbadura fun pelu nitori oro
ti won lo so si oludije fun ipo gomina labe egbe oselu naa, Dapo Abiodun.
Ninu atejade
ti egbe naa fi sita niluu Abeokuta, eyi ti Ogbeni Tunde Oladunjoye to je akowe
igbimo kiatika fowo si, lo ti so pe o ye kawon ba gomina naa kedun pupo.
O ni ko ye
kawon fun Gomina ni esi oro to so bi ki i ba se pe lori ero ayelujara lawon ti
gbo, tawon eeyan si n so pe o ye kawon naa soro, idi niyii tawon fi fee fun
lesi oro, nitori awon ko ka oro e naa kun tele.
Oladunjoye
wa so pe kaka kawon fun Amosun ni esi oro, se lawon pe awon eeyan lawujo ki won jo, ki won ba gomina naa kedun, ki won
si tun gbe ebe adura kale
O tun salaye pe ‘ Kaka to ye ka maa ba gomina
fa oro po, awa o ni se beee, bi ko se pee a o pe awon araalu, ki won jo ba
gomina kaaanu, ki won si tun gbadura fun nitori gbogbo nnkan to n se yii ko ma
baa daamu e leyin to ba fipo to wa sile.
“Fun gbogbo okan to ba fee maa si bi
Olorun lati maa so lokan ara e eni ti yoo di gomina, bi igba to ti ko esi ibo
sile iru eeyan bee o ye ka ti mo pe ki i soju lasan, a si ni lati kaaanu e
pupo, ko si ye ka maa ba iru e soro papo, sugbon aanu wa n se lori erongba e
lori Dapo Abiodun.
Akowe egbe naa tun so pe pelu gbogbo
bi Amosun atawon eeyan se n fojoojumo soro atako lori Dapo Abiodun, o ni o
fihan pe eru okunrin naa n bawon, ati jawe olubori e si ku igba die. O wa pari
oro e pe nnkan to je gbogbo omo egbe logun ni bayii ni lati jaawe olubori ninu
ibo to n bo naa ki i se lati maa fesi sawon oro ti ko nitumo.
|
No comments:
Post a Comment