Ariwajoye, oga akewi gba awoodu nla - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Wednesday 2 January 2019

Ariwajoye, oga akewi gba awoodu nla




Gbajumo akewi nni,Onarebu Bayo Oyebamji, topo awon eeyan mo si Ariwajoye ni won fun ni ami eye idanilola fun igbega asa ati ise lori ewi kike fodun 2018.

Nibi ayeye naa to waye lojo Abameta, Satide, ose to koja yii ni Sotubo, Sagamu nipinle Ogun. Ileeese Redeem to maa n gbe fiimu onigbagbo jade lo fun okunrin naa lakooko ti won sayeye ipari odun ti won maa n se.

Ariwajoye to ti gbe opo orin ewi jade lo gba awoodu fawon ipa ribiribi to ti fi ewi kike da lara, nipase gbigbe asa,ise, ati ogo Yoruba laruge.

Ninu oro to ba oniroyin wa so nibi ayeye, Bayo Oyebamji fi idunnu e han fun bi won se pon on le ti won foun lami eye naa, bo tile je pe okunrin naa so pe lojiji lo de ba oun.

O wa so pe pelu awoodu ti won foun yii, yoo je koun tun tera mo ebun ti Olorun foun yii ati pe lojoojumo toun ba ti ji ni bi igbega, idagbasoke yoo se da ile Yoruba maa n joba lokan oun, bee lo ni oun ko ni jawo nipa lilo ebun ti Olorun fi foun naa

Okunrin naa wa lo akoko naa lati so pe kaseeti ewi oun tuntun kan n bo laipe yii, eyi to pe akole e ni ironu omo oduduwa.

No comments:

Post a Comment

Pages