Oludije gomina labe egbe oselu YES, nipinle
Ogun, Ogbeni Sina Kawonise, ti so pe odun tuntun iyen 2019 ti won sese bere yii
lo ni yoo je odun ipanilaya fawon eeyan ipinle Ogun, o wa ro won lati wonu odun
naa pelu erongba gidi ati ayo.
Ninu atejade ti Doyin Owobamirin, to
je alakoso feto iroyin fun Sina Kawonise fi sita loruko oludije naa, eyi to fi
ki awon eeyan ipinle Ogun ku ewu odun tuntun, lo ti so pe igba die ni gbogbo
inira tawon eeyan ipinle naa koju lowo ijoba to wa lode yii ku.
O so pe ‘Akoko inira awon omo ipinle Ogun ko ni pe dopin mo, igba
die bayii lo ku nitori idi eyi ni mo se n ro awon eeyan lati wonu odun tuntun lo pelu ireti pipe, lati
pinnu gba ara won kuro lowo awon ota, ti won fara ni awon eeyan lati bi odun
meloo seyin, lati yeye won kuro nipase ibo wa lodun yii’.
Bi Kawonise se n ni kawon eeyan ni
ifokanbale fun ayipada rere bee lo ro won pe ki won fi kaadi alalope won iyen
PVC won le awon ti ko mu idagbasoke ba
won kuro lori ipo lati bi odun meloo seyin, ki won si dibo won feni ti won
nigbagbo ninu e pe o le se iyen egbe oselu Yes.
O ni "Pelu ibo wa, e je ka gba
ara wa sile leekan yii ati ni igba gbogbo, lati fi wa atunse fawon eeyan wa
nibi ibo ta a fee di naa, ija lati gbara wa sile lowo oro aje to so ni di eru,
ija ti ko ni ibon ninu.
O
wa ro awon eeyan ipinle Ogun lati dibo foun gege bi gomina labe egbe
oselu Yes, gege bi omoluabi to ni iberu Olorun, ati pe oun nikan ni oludije kan
soso ti ko ni babasale ninu oselu.
O ni gbogbo oro ipinle Ogun to ba wa
labe oun ni yoo je ti omo ipinle naa, ki i se fawon babasale kan ti won yoo joko
sibi kan, ti won yoo maa reti isakole lori nnkan to je tomo ipinle naa.
No comments:
Post a Comment