Gomina tele nipinle Ogun,Otunba Gbenga Daniel, ti so pelu idaniloju pe odun tuntun ta a sese bere yii yoo je odun ireti ati ileri ti yoo fopin si opo idojuko tawon omo orileede yii n koju lati nnkan bii odun meloo seyin.
O soro yii ninu ise odun to ran
sawon eeyan eyi ti Ogbeni Ayo Giwa to je oluranlowo fun un nipa eto iroyin gbe
jade loruko e, eni to tun je alakoso agba ipolongo Atiku lati di aare orileede
ohun tun salaye pe oun gboriyin fawon omo Naijiria fun igboya won, o si tun wa
dupe lowo won fawon iforiti ti won ti n ni bo seyin, o wa mu dawon loju pe
ayipada rere ati ilosiwaju yoo bere, niwon bi a ti n lo fun eto idibo.
Gbenga Daniel to tun je igbakeji
alaga, fun iplongo ibo aare nile Yoruba labe egbe oselu PDP tun so pe pelu
gbogbo bi nnkan ti n sele, awon omo orile-ede yii ti fihan agbaye pe awon le se
nnkan gidi lawujo ti ko ni mu iberu ati ifoya da ni lakooko yii.
O ni opo idojuko ta a ti n koju
laimo iye odun seyin ti to lati tun itan orileede ati ayanmo awon eeyan to n
gbe inu e ko ju bo se wa tele lo, opo idi lo so pe a ni lati ri pe a se atunse
sawon isele to ti waye saaju naa,eyi to so pe o le waye nipase erongba ati
ayipada rere.
Daniel tun so di mi mo pe opo
anfaani la ti soni nipase oro aje ati idagbasoke lawujo bii ina ijoba, ileese
nla, ipese ounje, eto ogbin, ilera ati eto eko, sugbon o ni ireti wa pe ninu
odun, ayipada rere yoo de ba awon nnkan wonyii ni Naijiria.
O wa gba awon omo orileede yii nimoran
lati sajoyo odun tuntun lona toooto, ki won si maa se iranti nnkan ti akoko naa
duro fun.
No comments:
Post a Comment