Ajodun apoti eri Aggomgombulabuyayah yoo bere - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday 30 December 2018

Ajodun apoti eri Aggomgombulabuyayah yoo bere 
Yemi Ogunbanjo

 Ajodun apoti eri Aggomgombulabuyayah to maa n waye lodoodun nijo Eeyan Kristi, iyen Unification of Christ People Mission to wa legbe ileese buredi Opemipo, Apata, niluu Ibadan yoo tun bere lojo Aiku, Sannde, ojo kefa, osu kin in ni, odun 2019 ti yoo si pari lojo ketala osu naa.

Gege bi atejade ti oludasile ijo naa, Eni- owo, Dokita Yemi Ogunbanjo fi sowo si wa lo ti so di mimo pe lojo kefa osu kin in ni naa ni akanse isin yoo waye fun ti ose eri naa Woli Omowonuola Inaolaji ni yoo waasu lojo naa. Ojo Aje, Monde, ti i se ojo keje, osu ni isoji apoti eri naa yoo bere  ti yoo si pari lojo Eti, Furaide.

Lale ojo Abameta, Satide, ojo kejila, ni aisun oba eri  Aggomgombulabuyayah naa yoo waye nigba ti isin yoo bere laago mewa ale,olorin emi nni, Segun Odusanya topo mo si aso funfun ni yoo waasu ti yoo sit un forin emi da awon eeyan lola.

Lojo Aiku, Sannde, ojo ketala ni asekagba ti apoti eri naa yoo jade, aago mejila osan ni isin yoo bere, Woli Segun Adeoye ni yoo si waasu lojo naa.

Eni owo, Dokita Yemi Ogunbamjo ni olugbalejo nigba ti Woli Goke Ogunsola tawon eeyan mo si I sho Pepper naa wa lara awon ti yoo forin emi dawon eeyan lola lawon ojo naa.

No comments:

Post a Comment

Pages