![]() |
Segun Showumi |
Laipe yii ni okunrin jade lati dupo
asoju-sofin niluu Abuja lati soju ekun Abeokuta South ninu ibo to n bo lodun
2019. Okunrin naa gbalejo oniroyin nile e to wa ni Abeokuta, ohun to ba wa so
niyii lati so Abeokuta di tuntun ju bo se wa tele lo.
Nnkan tawon araalu ri
lara mi ti won fi ni ki n jade
Mo dupe lowo
Olorun aarin awon eeyan ti mo fe loo soju fun ni mo n gbe, iwa rere ni mo si n
wu laaarin won. Gbogbo igba ni mo maa n wa pelu won, ti won ba ni nnkan se, mo
maa n da won lohun. Mo si n se nnkan ti mo lagbara lati se fun won, bi won se
wa yen, opo nnkan ti mo ni lo n bo si won lowo.
Mo feran
won, mo si maa n ri pe nigba ti ko si eto kankan tijoba se fun won lati ran won
lowo, ni mo se ro pe a fi kawa eeyan dide si won. Mo maa n fe ki won mo pe won
ni eeyan kan pe ti won ba de odo e yoo tan isoro won.
Nigba tawon
naa si rii pe mo ni akinkanju, mo si maa n duro nibi ki nnkan dara, mo si maa n
fe ilosiwaju niluu, mo si tun maa n gbiyanju lona to dara lati kopa to joju
lawujo, mo si ti n lo bii ogun odun laarin won ti mi o gbe apoti ibo ri, ti won
si maa n ri, bi mo se maa n se ti elomin in ba gbe apoti, ti mo maa n sare
siwaju, sare si osi , ti mo maa fori se, forun se fun won.
Awon funra
won lo wa pe mi pe eyi to wa nita yii, awon fee eni to maa gboro sawon lenu,
tawon naa yoo maa gbo tie. Ni mo se so pe Olorun a gba fun wa, ati pe emi naa
ti sakiyesi bi won se n se pelu mi ife yen sise pelu ara won ni. Aimoye
ogunlogo egbe lo ti wa ba mi pe Segun, to ba je ti ibo asoju sofin niluu Abuja,
iwo la maa dibo wa fun. Nitori won mo pe mi o ki i seeyan buruku bee ni mi o ki
I sonijagidijagan.
Lori wahala to n sele ninu PDP nipinle Ogun
Nnkan to sele ni pe ohun to n bawon leru gbodo ba emi naa
leru, sugbon eeyan ko gbodo ku sile de iku, a si gbodo maa ba ise lo ni, a si
ti mo pe oruko ti wa labe akoso Bayo Dayo ni won gbe jade gege bi oludije ti
won le dibo fun un. O si duro lori ofin pupo ati oro tile-ejo so.
A o gbodo se nnkan tonikaluku yoo fi maa se ohun to ba wuu
lai bowo fun ofin. Iyen ni mo ri, ti mo si tun mo pe won feran mi, o si da mi
loju pe laarin odun meloo, won yoo pari gbogbo gbonmi –si- omi- o- to to n sele
ninu egbe naa.
Ibi ti won ba si fi ori e ti si, gbogbo wa naa lo ma foju wa
ri sugbon mo nigbagbo pe didun losan yoo so, nitori ibi ti mo wa, ibi ti ona wa
ni.
Emi o tie ki i bawon se nnkan to ba yapa, idi ti mo fi so bee
nip e a o le so pe ki awa laaarin ilu, ka ma wo ibi ti ofin wa, iyen ni yoo je
olutoni lati mo nnkan to ye ko se. A fi ki Olorun ba wad a si oro oselu, nitori
ki i se nnkan to dara kawon olori egbe maa da nnkan ru lati oke. Nitori e ni
gbogbo e se n se jagajaga, ati otun ati osi.
Idi tawon eeyan fi ni ki jade dupo asoju-sofin niluu Abuja
Idi tawon eeyan fi ni ki n jade ni fun ekun Abeokuta South
nile igbimo asoju-sofin niluu Abuja nip e kin ni ka ti gbo pe Abeokuta to je
oluulu ilu Egba, a maa wa laaarin gbagede awon akegbe wa, a o ni le soro pe
nnkan bayii la n fe fawon eeyan wa, iru nnkan bayii, ni a ro to si je mi logun
pupo, nitori o ti to akoko, A ni lati to omo wa nipa eto eko,lati le je ki won
mo nnkan to n lo ni agbaye.
Bee ni mo tun n ro pe awa naa ti to ni osibitu nla meji, mo
tun ro pe o ye ki a mu ere idaraya lokunkundun nile Egba lona ti yoo fi di
okoowo fun wa.Mo tun roo pe a gbodo ni asa kan, ti gbogbo aye yoo ma wa ba wa da
si. Eyi to wa je mi logun ju lo, to se koko nip e, ko te mi lorun bawon eeyan
wa ko se lowo lowo. O ye kawon eeyan ni nnkan ti won maa fi sise, ti won maa fi
bo ara won. Ogbon ti a maa da lati je ki won maa ri nnkan se. A o si da si bi
won se n seto ilu, ti okan gbogbo ilu yoo bale. Mo nigbagbo pe gbogbo nnkan
meremere ti a fee gbe se, Olorun a gba fun wa.
Mo tun maa bawon si ofin eyi ti yoo dekun bi won se n mu ogun
oloro,yato si pe won maa mu awon to n mu, awon to ba n ta gan-an gbodo jiya
labe ofin. Mo fee je ki a pada sipo olori ti a je, olori yen, awon omo ibe lo
le je ka debe nigba ti a ba se nnkan gbogbo to ye ka se.
Emi o si fee de Abuja ti yoo wa ma da ipinle laamu, nitori mi
o fe ki won da Abeokuta laamu. Bii pe ki gbogbo nnkan maa lo letoleto.Mi o si
ni boruko mi je lai ati lailai.
Lori ki won dibo fun oruko oludije tabi egbe
Mejeeji naa ni, to ba ni ko dibo fun oruko sugbon won ko gba
oludije aladaani ti ko ni si labe egbe kankan.Nnkan to wa n sele bi mo se n wo
ibo odun 2019, afaimo ko ma je pe oruko lawon eeyan yoo dibo fun laiwo egbe to
ti jade. O si ba emi naa lara mu, nitori mi o fe ki won maa fawon radarada
eeyan sipo. Eni ti ko ye a o gbodo fun amo, eni to ba ye ka dibo gbe e wole,
igbagbo temi niyen.
Nipa ka maa fowo ra ibo
Ki Olorun ko gba wa lowo osi ati ise, ki I se pe a n mu owo
yen teletele a
fi n ra ibo, a kan maa n fowo se pe won
fee ki eeyan jade, won fee ra epo si moto sugbon nigba tawon ijoba APC de be ti
won se bee ni Ekiti ati Osun, tawon eeyan bere si ni rii ti won ba owo yen je. A
gbodo fofin de, ki won bawon to n se iru nnkan bee wi.
A gbodo gbagbo ni ajo INEC
Bi a ko ba gbagbo ninu ajo INEC ta ni a wa fee gbagbo ninu e
to maa ba wa seto ibo, ebe la maa be won, ki won jo, ki won ro ojo ola ni.Ki gbogbo
e lo nirowo rese.
Amoran mi fawon eeyan mi ni Abeokuta South
Mo be eyin gbogbo eeyan mi ni Abeokuta South, mo be yin ki e
gba rukutu ti mi lati wole sipo asoju-sofin, mo si seleri pe mi o ni doju ti
yin,,Olorun ko ni doju ti yin.
No comments:
Post a Comment