Rotimi Paseda oludije gomina to kun oju osuwon nipinle Ogun - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday 28 December 2018

Rotimi Paseda oludije gomina to kun oju osuwon nipinle Ogun
Paseda
Lodun 2014, ni irawo okunrin oloselu kan jade, opo awon eeyan ni ko mon on tele, Otunba Rotimi Paseda lo n je, akikanju lawujo awon eeyan pataki ni lawujo, ko to gbe igba oselu labe egbe oselu Unity Party of Nigeria, UPN, ni Olorun ti foun gbogbo ke.
Nnkan to ya awon eeyan lenu ni pe laarin osu kan si meji ti egbe oselu UPN fi pada leyin aimoye odun ti won ko fi gburo e mo, awon eeyan bere si nifee egbe naa.
Ko si selomin in to n gbo bukata egbe oselu naa bi ko se okunrin ti won pe ni Paseda yii, bo tile je pe leyin ti won fa kale gege bi oludije gomina lodun naa lawon kan dide ote ti won si da egbe si meji sugbon leyin oreyin, gbogbo won fi mo sokan lati sise pelu e.
Ohun iyalenu lo je nipinle Ogun pe leyin bi osu meji si meta ti ibo yoo fi waye lodun 2015 lokunrin yii bere ipolongo e, o si tun rowo mu ju awon ti won ti bere saaju e lo. Ipo keta lo se nigba naa.
Ohun tawon araalu so nigba naa ni pe akoni lokunrin naa, ka ni o ni egbe oselu to lenu nibe ju UPN lo, o seese ko rowo mu gege bi gomina nigba naa.
Lojo kan, ninu osu kin in ni, odun 2015, lakooko ti won seto ariyanjiyan itagbangba fawon oludije gomina, Amosun to je Gomina, toun naa dije fun eleekeji so pe ka ni oore ofe wa foun lati gbe ijoba feni to ba wu oun ni, Paseda loun ko ba gbe e fun nitori olopolo pipe eda ti oye ipo naa ye ni.
Lati odun 2015, ti ibo naa ti koja, Paseda ko sa seyin leyin gbogbo eto e lati mu inu araalu dun, to fi mo awon omode, ireti e ni pe boun ba di gomina lodun 2019 oun yoo le se ju bee lo.
Idi tawon eeyan fi n foju sona lati mo egbe oselu ti yoo ba jade ko le fi rowo mu, bawon kan se n so pe APC ni yoo ba jade, awon kan ni PDP, nigba to ya won ni egbe oselu ADC nitori ti won roun ati Gboyega Naisir Isiaka iyen GNI papo.
Sugbon lojiji la gbo pe okunrin naa ti kuro ninu egbe oselu UPN, o si ti jade labe egbe oselu SDP, ibeeere tawon eeyan n beere lowo ara won ni pe SDP ke, pelu gbogbo egbe oselu ti won n gbo oruko e, o se wa je SDP.
Bi a ba ni awon to soro ko ri so, iro la n pa, nitori loooto legbe naa ti wa tipe, bi a ko ba si gbagbe abe egbe oselu naa ni Oloye MKO Abiola ti wole fun ipo aare lojo kejila, osu kefa, odun 1993.
Sugbon nigba ti won ti fagile egbe naa ni ko ti gbe ri mo, bo tile je pe awon kan si n wa oko egbe naa, o fee je pe ko siyato laarin egbe naa ati UPN.
Iwadii fi ye wa pe latigba ti Paseda ti di oludije fun ipo gomina labe egbe oselu naa, lo ti n se ipolongo e labele, to si n so fawon eeyan nnkan to ni lokan lati se, won ni ko tii maa se nigbangba.
Ohun tawon araalu wa n so ni pe pelu bi okunrin yii se kun oju osuwon, to si ni itara lati di gomina, o se wa je egbe oselu ni yoo maa ja ni tan an mo. Ki okunrin ma je ko yaa lenu pe bi ibo ba ti ku ose meji lawon kan ninu egbe naa yoo maa pariwo pe awon setan lati sise po pelu APC, tabi ADC tabi PDP, nitori won ko nigbagbo ninu egbe oselu won. Oju lasani ni won si n se.No comments:

Post a Comment

Pages