Sina Kawonise |
Oludije gomina labe egbe oselu YES
nipinle Ogun, Ogbeni Sina Kawonise ti ro awon eeyan nipinle Ogun pe bi nnkan ba
n ri, bo se n ri yii ti airise fi gbogbo igba buru si,ti ko si eto abo to peye,
ti iponju awon eeyan n po o ye ki won tete wa ona abayori lati fopin sawon
nnkan wonyii.
O soro yii lakooko to n ki awon
eeyan ku ayeye odun keresi, eyi ti Doyin Owobamirin fi atejade e sita loruko e.
O ki gbogbo awon omo ipinle Ogun ku oriire pe won tun ri odun keresi layo, bo
se n ki won bee naa lo n gba won lamoran lati je oluralowo lona gbogbo.
Gege bo se wi, o ni ko ye kawon
eeyan so ireti nu bi ko se pe ki lo anfaani ti won ni lati jade dibo lodun
2019, o ni bi won ba le yan eni to wu won, to ni iberu Olorun, o da oun loju pe
ayipada rere yoo de ba ijoba ati igbe aye onikaluku.
Kawonise to ti figba kan je
komisanna feto iroyin nipinle Ogun tun so pe “Akoko ti a way ii, a gbodo lo
anfaani lati ro bi a se ba ara wa nibi taa way ii lori bi awon ti ko to oju
osuwon ti n dari wa lona ti ko to. A sit un gbodo wa lo anfaani to wa lowo way
ii lati fi yan asaaju toooto ti yoo ni iberu Olorun, ti yoo mu ekun wa pada bo
si eri, ki a si fibo wa gbe e wole.
Oludije naa tun salaye siwaju pe
iriri taa ti koja ti ko wa pe gbogbo awon ti a ti fun ni oore ofe lati mu ise
ati iponju kuro lara awon eeyan ni won si agbara naa lo, ti won se ijoba ti ko
nitumo tie to abo mehe, tawon eeyan ko si je anfaani mundunmundun ijoba
tiwantiwa.
|
No comments:
Post a Comment