Lati nnkan bii aago marun un idaji
lawon eeyan ti n tu yaya loo sile ijosin ile isura ti Olorun iyen Treasure
House of God, to wa lona Quarry, Abeoku ta, nipinle Ogun, lojo odun keresi nibi
ti won ti bo egberun mefa eeyan lojo odun keresi, nipa fi fun won lounje odun
loo sile.
Bo tile je pe igba akoko ko niyii ti
won yoo se iru nnkan bee sugbon todun yii yato nitori agbara won fee ka awon
eeyan ti won wa nibe, nitori bi won se po to.
Ki i se nitori ounje ti won fee fun
won ni agbara won ko kaa o amo lati seto fawon eeyan naa ko ma ba da wahala
sile, ise kekere ko si lawon ti won wa fun eto abo lojo naa se, bi ki i ba se
bee awon omoota ko so pe awon ko da gbogbo e ru lojo naa.
Eto ti won se naa ti won pe akole e
ni ‘Jesu bo awon eeyan’ lawon naa wo akose e lati fi mu inu awon eeyan dun
laifi se elesin de, nitori pe bawon onigbagbo se wa nibe bee lawon musulumi ko
fa seyin lojo naa, ti gbogbo won si mu ebun loo sile.
Iwadii wa fi ye wa pe pataki nnkan ti oludasile ijo naa, Pasito Senfuye fi
sagbekale eto olodoodun naa ni kawon eeyan naa maa fi ayo sodun, ki won si mo
pe awon wa a laaye tawon si begbe pe.
Bii egberun merin awon eeyan ni won seto
naa fun lodun to koja, ti won si nii lero pe won yoo se fun egberun marun un,
amo nigba ti won rii pe awon eeyan po ju bi won se lero loo, ni won kuku fi
febun ta egberun mefa, tiwadi tun fi ye wa po o ju bee lo lore.
Ninu
oro Diakoni Kayode Ogunjimi to je alaga igbimo eto naa. O so pe ti mura sile pelu awon eeyan e. O ni okan lara
ijihinrere okan lawon seto naa fun.
|
No comments:
Post a Comment