Gbenga Daniel ni idaloju ayipada ireti n bo wa lorileede yii - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Tuesday 25 December 2018

Gbenga Daniel ni idaloju ayipada ireti n bo wa lorileede yii



Otunba Gbenga Daniel, to je gomina tele lorileede yii,  ti muu da awon eeyan orileede yii loju pe ayipada rere ijoba tuntun ti yoo faye gba mudunmudun ijoba tiwantiwa, ti yoo si tun mu itumo gidi wa, tawon araalu yoo maa gbe ni igbe alaafia si tun n pada bo.

O soro yii lakooko to ki awon eeyan orileede yii ku ayeye odun keresi, ninu ise to ran naa, eyi ti Ayo Giwa, to je oluranlowo e nipa iroyin e fi sita loruko okunrin naa lo ti so pe oun bawon omoleyin sajoyo odun keresi, pelu eko to ko wa nigba igbe aye Jesu. O wa gba awon niyanju lati je ki ihuwasi gege bi onigbagbo rere han ninu aye won.

O ni bo tile je pe awon omo orileede yii ti foju wina ainifokanbale, pelu opo idojuko to n koju won lorisirisi ona sugbon pelu igbagbo tawon , eeyan ni je ki ireti wa pe nnkan si bo wa dara lojo iwaju.


Eni to tun je igbakeji alaga ipolongo fun Abubakar Atiku fun ipo Aare nile Yoruba tun so pe "Gege bi a se n se ajoyo odun keresi, ti a si n woo dun tuntun lookan, to tun je odun ti idibo yoo waye, a ni lati se ipinnu
Lati rii pe a yan asaaju to le fopin si gbogbo aini abo to peye lorileede yii, ti yoo sit un oro aje wa se bo se ye’

Bakan naa ni Gbenga Daniel tun so pe bi odun se n lo sopin, o ni kawon araalu rii pe won foju si ireti rere ti yoo mu igbe aye rorun, ki won si se ileri ti yoo mu alaafia ba awon akegbe won laarin awon elesin, oloselu atawon eleyameya, ki nnkan ta n fe le te wa lowo.


No comments:

Post a Comment

Pages